Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ Oyedele ti ṣapejuwe Onijoun tiluu Ijoun, Ọba Rasak Babatunde Adewusi to waja laipẹ yi gẹgẹ bi olufọkansin toootọ, ti ipa rere rẹ ko nii parẹ titi lai.
Onimọ-ẹrọ Salakọ Oyedele to ṣoju Gomina Dapọ Abiọdun lo sọrọ naa nibi eto adura ọjọ kẹjọ ti wọn ṣe fun Oloogbe naa, eyi to waye niluu Ijoun to wa nijọba ibilẹ Ariwa Yewa, ipinlẹ Ogun.
O sọ pe gbogbo ipa ati agbara ni Ọba to waja naa fi sin ilu rẹ, paapaa ipinlẹ Ogun, to si ni titi lai lawọn araalu Ijoun atawọn ọmọ ipinlẹ naa yoo ma a fi ṣeranti ẹ.
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati tun gbogbo awọn ileewe to wa kaakiri ijọba ibilẹ nipinlẹ Ogun ṣe, eyi ti yoo si jẹ ki wón le maa figagbaga pẹluu awọn ileewe igbalode yooku lagbaye.
Nigba toun naa n gba ẹnu awọn Oloye ilu Ijoun sọrọ, Adele Onijoun, Oloye Alani Ọlalẹyẹ dupẹ gidigidi lọwọ Ọlọrun fun igbe aye Oloogbe naa, to si fidi ẹ mulẹ pe Ọba Onijoun ana kii ṣe ojuṣaaju ẹnikẹni ko too waja, to si tun sọ pe ọgbọn imọ ati oye to wa lori Ọba naa kii ṣe kekere, eyi to sọ pe o lo lati fi tukọ ilu naa pẹluu alaafia ati iṣọkan.
Ọjọ keji oṣu keje ni Onijoun waja, to si jẹ pe lẹyin oṣu kan gbako, iyẹn ọjọ kinni oṣu ni wọn sin in nilana Musulumi.
No comments:
Post a Comment