Titi ayeraye lawọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea atawọn ololufẹ wọn kaakiri agbaye ko fi ni i gbagbe iya manigbagbe ti wọn jẹ lọwọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United lọjọ Aiku Sande ana.
Ko si nnkan meji ti yoo jẹ kawọn ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea maa ranti iya manigbagbe naa bi ko ṣe pe ọjọ ọdun Ileya tawọn Musulumi kaakiri agbaye maa n ṣe ni, to si tun jẹ pe ibẹrẹ saa tuntun ni ifigagbaga ti Premier League naa jẹ.
O ṣeni laanu pe titi dasiko ti a kọ iroyin yi tan lọpọ awọn Chelsea ko tii le jẹun daadaa, to si jẹ pe ṣe lo ba ọdun naa jẹ fun wọn, latari bi Manchester United ṣe fi agba han wọn lẹkunrẹrẹ pẹluu aami ayo mẹrin si odo.
Àmì ayò méjì ni Marcus Rashford
fi sẹ ogun Frank Lampard nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́yìn to gba iṣẹ́
akanimọ̀ọ́gbá Chelsea àti àwọn ọmọ ẹyìn rẹ̀ ní ìpele ìkíní àti ìkejì.
Anthony Martial àti Daniel James náà ràn Red Devil lọ́wọ́ láti jáwe olúbori Chelsea ninu ìdíje tó dabi pé
ó fẹ́ kó Chelsea lóyìí ojú.
Ìyàlẹ́nu ní abájáde ìfẹsẹwọnsẹ̀
ọ̀hun jẹ́ nítori ó jọ bi ẹni pé Chelsea yóò ṣe dáradár jú Manchester United lọ
ní sáà àkọ́kọ́, bọ́ọ̀lù ṣe gbá àwsn pada ní ẹ̀ẹ̀mejì bi Emerson àti Tammy
Abraham ṣe gbìyànjú tó.
O jọ bi ẹní pe àwọn olólùfẹ́
Manchester United ko ni fi bẹ́ẹ̀ ba Chelsea kẹ́dùn bí ìdíje yìí ṣe jẹ èsì tó
tíì dára júlọ ni old Trafford pẹ̀lú Chelsea láti ọdun 1965.
No comments:
Post a Comment