Titi dasiko ti a kọ iroyin yi tan, lawọn eeyan ṣi n fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si Kọmiṣana fọrọ epo rọbi ati idagbasoke, iyẹn Oil Producing Area Development
Commission (ASOPADEC) nipinlẹ Abia, Ọnọrebu Adeile Ekeke.
Ọjọ Sannde to kọja ni Ọnọrebu Ekeke padanu iyawo ẹ ati ọmọ meji sinu ijamba mọto lopopona Enugu-Okigwe, lasiko ti wọn n rin irin ajo, ko too di pe ijamba naa waye lojiji.
Loju ẹsẹ ni gbogbo wọn ti dagbere faye, to si mu kawọn eeyan kawọ mọri. Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn la gbọ pe wọn gbe wọn lọ si mọṣuari, to si jẹ pe ana tii ṣe Tuside ni wọn sin wọn.
Ile-iṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL lo n gbe IROYIN AWIKONKO jade pẹlu ontẹ Ijọba orilẹ-ede Naijiria labẹ ajọ iforukọsilẹ nni, iyẹn CORPORATE AFFAIRS COMMISSION. A fẹ ki ẹyin ti ẹ n ka Iroyin Awikonko mọ daju pe a ko ni i gba ẹnikẹni laaye lati ṣe ẹda iroyin wa, tabi gbe e jade ninu iwe iroyin min in lai gba aṣẹ lọwọ awọn alaṣẹ wa, ẹsẹ ofin la o fi gbe onitọhun. Bẹẹ, a ko ni fẹ ki ẹnikẹni ṣi iroyin wa ka, nitori pe iwadii kikun la n ṣe ka to le gbe iroyin jade, nitori naa, bi ẹ ba ka ifọrọwerọ pẹlu eeyan, ohun ti ẹni naa ba sọ, ki i ṣe awa la sọ ọ, ẹni naa lo sọ bẹẹ. Fun alaye lẹkunrẹrẹ, tabi ipolowo ọja yin, ẹ le kan si wa lori: +2347012342712.
No comments:
Post a Comment