NITORI ỌRẸKUNRIN RẸ KỌ Ọ SILẸ, ỌMỌDUN MẸRINLA POKUNSO NI DELTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 10, 2019

NITORI ỌRẸKUNRIN RẸ KỌ Ọ SILẸ, ỌMỌDUN MẸRINLA POKUNSO NI DELTA

Ko sẹni to tete gbagbọ nigba tiroyin kan jade sita pe ọmọdebinrin ọmọdun mẹrinla kan, Favour gba ẹmi ara rẹ, nipa bo ṣe pokunso, to si n jẹkayeefi nipa nnkan to ro debẹ.

Ipele kẹrin (SS1) la gbọ pe Favour wa nileewe girama Kess College to wa ladugbo Ekredjebor lagbegbe Ughelli, to wa nijọba ibilẹ Ariwa Ughelli, ipinlẹ Delta.

Ohun ta a gbọ ni pe ọrẹkunrin Favour lo ja a ju silẹ lojiji pe oun ko ṣe mọ, to si jẹ pe gbogbo akitiyan ati igbesẹ ti wọn ni favour gbe lati jẹ ki ololufẹ rẹ naa gba a pada lo ja si pabo, eyi lo fa a ti wọn loo fi pinu lati wo o pe iku ya ju ẹsin lọ.

AWIKONKO gbọ pe Favour nikan ni ọmọ kan ṣoṣo ti iya ati baba rẹ bi, to si jẹ lẹta to kọ silẹ ko too pokunso lo tu aṣiri iku to pa a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI