NIBI TI PASITỌ TI N WAASU IHINRERE LO TUN TI JI FOONU N'IBADAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 25, 2019

NIBI TI PASITỌ TI N WAASU IHINRERE LO TUN TI JI FOONU N'IBADAN

Ọrọ buruku toun tẹrin, nigba ti wọn ka Ajihinrere kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Akinjide Durojaiye mọ ibi to ti n ji foonu lasiko to n waasu ihinrere Jesu pe kawọn eeyan yi pada kuro ninu ẹṣẹ wọn.

"Ẹ ṣe mi jẹjẹ, iṣẹ eṣu ni, Ẹmi mimọ lo ran mi niṣẹ" lọrọ ẹbẹ to n tẹnu Durojaiye jade lasiko tọwọ palaba ẹ segi naa, pẹlu foonu olowo nla meji ọtọọtọ to ji gbe lagbegbe Dugbẹ niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, opin ọsẹ to kọja yi la gbọ pe Durojaiye ti wọn ni ilu Ilarẹ-Ijẹṣa to wa nipinlẹ Ọṣun lo ti n ṣiṣẹ ni ṣọọṣi kan ti wọn pe ni Dominion Assembly gba ilu Ibadan lọ, to si lọ n waasu ihinrere Jesu.

Wọn ni bi Durojaie, ọmọdun mọkandinlaadọta naa ṣe de agbegbe Dugbẹ lọjọ naa, ni wọn loo bẹrẹ sii waasu loirṣiriṣi, tawọn eeyan si n wo o bo ṣe n ṣe. Ṣadede ni wọn loo wọ ṣọọbu kan ti wọn pe ni Fẹmi Johnson.

Bo ṣe de bẹ la gbọ pe o fọgbọn yọ foonu meji ninu awọn foonu ti wọn n ta, ti wọn si lowo awọn foonu naa ko din ni ẹgbẹrun lọna aadọrin (N70,000) naira, ti ko si mọ pe awọn eeyan n ṣọ oun.

AWIKONKO gbọ pe bo ṣe ji foonu naa lo ba ẹsẹ rẹ sọrọ, ti wọn si lee mu. Nibi ti wọn ti n luu lo ti bẹrẹ sii ka bi ajẹ boroboro pe ara ọmọ oun to jẹ ọmọdun meje ni ko ya, eyi lo jẹ koun wa ọna lati ri owo ji.

Igbe ti wọn ni ọkunrin naa n ke lo mu kawọn ẹlẹyinju aanu baa bẹbẹ, ti wọn si pada fii silẹ, pe ko maa lọ layọ ati alaafia.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI