Aarẹ Muhammadu Buhariti fidi ẹ mulẹ pe awọn ti ko din ni miliọnu marun lawọn ọmọ Naijiria tijọba oun ti yọ kuro ninu iṣẹ ati oṣi pẹluu agbekalẹ eto National Social Investment Programme (NSIP) tawọn gbe kalẹ lọdun mẹta sẹyin.
Nibi apejọ Global Youth Employment Forum eyi ti ajọ International Labour Organisation (ILO) niluu Abuja ṣagbatẹru rẹ l'Ọjọbọ Tọside ana ni aarẹ Muhammadu Buhari ti sọrọ naa pe awọn anfaani iṣẹ ti ko din ni miliọnu meji lawọn pese.
Nigba to n gba ẹnu Aarẹ Buahari sọrọ, akọwe ijọba apapọ, Boss Mustapha sọ pe nigba tawọn gbajọba lọdun 2015 lawọn ti ṣagbekalẹ eto iṣẹ ti ko din ni miliọnu meji fawọn araalu, to si jẹ ko yọ pupọ awọn eeyan kuro ninu iṣẹ ati oṣi to n ba wọn finra.
No comments:
Post a Comment