Rẹkitọ ile ẹkọ giga gbogboniṣe ti Moshood Abiọla, Dọkitọ Samson Ọdẹdina ti sọ jẹ ko di mimọ fun gbogbo agbaye pe ile ẹkọ MAPOLY tuntun ti bẹrẹ bayii, to si ti bẹrẹ lati figagbaga pẹluu awọn akẹgbẹ rẹ kaakiri agbaye.
Dọkitọ Samson Ọdẹdina sọ pe MAPOLY tuntun yi ti de lati wa ni ipo aṣaaju to wa lọdun meloo kan sẹyin, lai sẹni ti yoo ni agbara lati le e ba.
Ọjọbọ tii ṣe Tọside ni Dọkitọ Samson sọrọ yi sita nibi ifilọlẹ to ti n gba awọn akẹkọọ tuntun ti ko din ni ẹgbẹrun kan aabo (over 5000) fun saa ikẹkọọ ọdun 2018 si ọdun 2019 wọle, iyẹn fun ipele ND ati HND, eto naa lo waye ninu gbangọn ayẹyẹ OGD to wa ninu ọgba ile ẹkọ naa.
O ni ile ẹkọ naa ti ṣe tan lati tun jẹ ki orukọ rẹ pada si ipo to wa nigba kan ri, nipa imọ ẹrọ igbalode ati ayelujara, ati ẹka ikẹkọọ wọn, ti ko si nii si ile ẹkọ min in to maa le duro lati ba a figagbaga nilẹ adulawọ ati lagbaaye.
Bẹẹ lo tun fidi ẹ mulẹ pe Redio MAPOLY ti bẹrẹ iṣẹ, iyẹn lẹyin ti ajọ igbohunsafẹfẹ lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn Natinal Broadcating Commission (NBC) ti fontẹ luu pẹluu 99.7FM.
O jẹ ko di mimọ pe awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ti gbe igbimọ dide lori ọna ti Redio MAPOLY 99.7FM yoo gba bẹrẹ iṣẹ laarin ọsẹ mẹrin pere, tawọn akẹkọọ yoo si maa mọ idi pataki ti wọn fi n wa si ile-ẹkọ naa.
No comments:
Post a Comment