LẸYIN ỌDUN MEJILA, FATHIA ATI SAIDI BALOGUN PADE LOKO ERE, BẸẸ NI WỌN ṢERE IFẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 17, 2019

LẸYIN ỌDUN MEJILA, FATHIA ATI SAIDI BALOGUN PADE LOKO ERE, BẸẸ NI WỌN ṢERE IFẸ

Orin 'Ija d'opin, ogun si tan, Olugbala jagun m'olu, orin ayọ lao ma kọ, Aleluya' lọpọ awọn eeyan mu sẹnu lai pẹ yi nigba ti wọn ri awọn ololufẹ tẹlẹ nni, Saidi Balogun ati Fathia Balogun (Williams) loko ere, tawọn mejeeji si jọ ọ kopa papọ, ko da, ti wọn tun ṣere ifẹ diẹ lọjọ naa.

Ohun ta a gbọ ni pe inu fiimu kan ti wọn n ya lọwọ, iyẹn Ajẹ Ọja lawọn mejeeji ti pade, ti wọn si gba lati jọ kopa papọ.

Iyalẹnu la gbọ pe o jẹ fawọn eeyan nigba ti wọn ri awọn mejeeji papọ, ti wọn si gba lati jọ kopa ninu fiimu naa.

AWIKONKO gbọ pe igbesẹ ti n lọ lọwọ bayii laarin awọn agbaagba kan lati bawọn ololufẹ mejeeji pari aawọ to wa laarin wọn, lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti gbiyanju lati ba wọn pari ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI