Gbogbo eto lo ti to bayii fun fun ilu Ibadan lati
gbawọn alejo nla-nla nibi ti awọn ẹbi Adeṣigbin ti maa ṣe akanṣe adura Fidau fun Mama
wọn, Alaaja Afusat Adukẹ Adeṣigbin lẹyin ọdun kan to d'oloogbe.
Ninu atẹjade to tẹ AWIKONKO lọwọ lonii ni wọn ti fidi ẹ mulẹ wi
pe, lati awọn iluu bii London, Italy, Ireland; Amẹrika atawọn orilẹ-ede nla min-in kaakiri
agbaye lawọn eeyan ti maa wa, bẹẹ lawọn to wa ni Naijiria naa ko ni i gbẹyin nibẹ
rara.
Gbọngan nla ti ile ẹkọ girama Lagelu, iyẹn Grammar School lagbegbe Lagelu Agugu
n’Ibadan ni eto pataki yii yoo ti waye, bẹrẹ lati aago mẹwaa aarọ si mẹrin
irọlẹ nibi ti awọn Aafa nla-nla yoo ti peju-pesẹ lati ṣadura fun Oloogbe ọhun.
Bẹẹ gẹgẹ ni itọju awọn alejo yoo waye pẹluu ni gbagede ọhun.
Ninu ọrọ ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe yii, Ọgbẹni
Ademọla Adeṣigbin lo ti ṣapejuwe Mama naa gẹgẹ bi i abiyamọ toootọ, to gbiyanju
lati tọ awọn ọmọ ẹ daadaa ki wọn le ni ọjọ ọla to dara.
O ni, “Gẹgẹ bi igbagbọ awa Musulumi, ohun kan ti a le maa ṣe fun awọn oku ọrun wa naa ni iranti wọn pẹlu adura ati itọre aanu lorukọ wọn. Iya wa ṣe daadaa pupọ, ẹni ti a ko si le gbagbe laelae ni, ki Ọlọrun tubọ ba wa fi alijanna onidẹra kẹ wọn.”
Lara awọn ọmọ to gbẹyin Mama naa niwọnyi; Ismail
Ademọla Adeṣigbin; Mọrufat, Musbaudeen, Mọruf, Lateefah; Mọrufat, Idowu, Mutiu
Ishọla atawọn ẹbi; ara, ọmọ-ọmọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Kaakiri lawọn ololufe Alaaji Sikiru Ayinde Barrister, iyẹn awọn ọmọ ẹgbẹ
Barybration Association kaakiri agbaye, eyi ti Ademọla Adeṣigbin jẹ baba ẹgbẹ
fun yoo ti wa.
No comments:
Post a Comment