ILE TO WO DANU L'EKOO, WỌN NI KII ṢOJU LASAN (FỌTO) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 2, 2019

ILE TO WO DANU L'EKOO, WỌN NI KII ṢOJU LASAN (FỌTO)

Iyalẹnu lọrọ ile to wo lagbegbe Gbagada niluu Eko lọjọ Tọside ana ṣi n jẹ fawọn eeyan kaakiri agbaye.

 
Ojule kẹrinlelogun, adugbo Adio nitosi New Garage Bus stop, Gbagada niṣẹlẹ naa ti waye nigba ti wọn sọ pe aarọ kutu nile naa deede da wo nibẹrẹ oṣu kẹjọ ti a wa yii.

 
Loju ẹsẹ la gbọ pe awọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Ekoo, iyẹn LASEMA ti sare debẹ lati doola ẹmi awọn to wa ninu ati nitosi ile naa.

 
Ẹnikan ṣoṣo ti wọn lọmọdun mọkanlelogun pere la gbọ pe o kagbako ninu ijamba ile to wo naa, to si jẹ pe ọsibitu to ti n gba itọju lo wa dasiko yi.

 
Ohun to n ṣe awọn eeyan ni kayeefi ni pe baba onile naa ti jawe jade kuro nile mi fawọn to n gbe ninu ile naa, laatri awọn akiyesi ti wọn loo ti ṣe lara ile naa, ṣugbọn ti wọn lawọn to n gbe inu ile naa ko gbọ.

 
A tun gbọ pe loṣu mẹta sẹyin ni onile naa tun pada wa lati le awọn eeyan naa jade, ṣugbọn ti wọn lawọn to n gbe ile naa sọ pe ko tii si owo lọwọ wọn lati fi gba ile min in, ko too di pe ijamba naa ṣẹlẹ lojiji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI