Gọmina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun ti jẹ ko di mimọ pe ijọba ilu ko ṣe e da ṣe lai si imọ ati ọgbọn awọn agbaagba ilu nibẹ, nitori naa, o sọ pe idi ni yii toun yoo fi ya ninu imọ ati ọgbọn awọn agbaagba lati le rii pe ipinlẹ naa gun oke ju bi ẹnikẹni ṣe le lero lọ.
Gomina Abiọdun lo sọrọ naa lonii niluu Abẹokuta, lasiko to n gba ẹgbẹ awọn igbimọ agbaagba lalejo ninu ọfiisi rẹ to wa ni Oke-Mọsan. Nibẹ lo si ti sọ pe oun ko ni i koyan agba kankan, paapaa awọn obinrin kere lati da si eto iṣejọba oun.
Bakan naa lo tun sọ pe anfaani nla lo jẹ fun ipinlẹ Ogun lati ni awọn agbaagba bi i eyi, iyẹn State Elders Consultative Forum, nitori pe awọn gan an ni majẹobajẹ ti wọn duro digbi ti ijọba, ti wọn ko si ni gba ki ipinlẹ naa relẹ laarin awọn akẹgbẹ ẹ.
Nigba toun naa n gba awọn yooku sọrọ, Onidajọ fẹyinti Bọla ajibọla to jẹ alaga ẹgbẹ igbimọ awọn agbaagba naa, ẹni ti Olori Yetunde Gbadebọ ṣoju fun sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ naa jẹ awọn agbaagba to ṣe e mu yangan lawujọ, paapaa awọn ti wọn ti ko ipa ribiribi nipinlẹ Ogun ati orilẹede Naijiria, eyi ti wọn ni gbagbọ pe wọn yoo ran ijọba Dapọ Abiọdun lọwọ.
No comments:
Post a Comment