Atẹwọ ati ariwo Áleluya lo gba ọkan gbogbo awọn ọmọ ijọ ori oke ina ati iṣẹ iyanu jakejado nigba ti Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun gun pẹpẹ lati ṣe idupẹ idibo to gbe e wọlẹ loṣu kẹta ọdun yi.
Opin ọsẹ to kọja yi, iyẹn lasiko eto adura ibẹrẹ oṣu to ma n waye, eyi ti wọn pe ni Agbara Gbọdọ Paarọ Ọwọ, iyen Power Musta Change Hands Programme, ti oṣu yi ni Gomina Abiọdun lọ ṣe idupẹ naa.
To si ni o ti wa ninu eto oun lati wa a fi ẹmi imoore han si Ọlọrun, tori pe oun ko ni ẹlomin in toun n ke pe bi ko ṣe Ọlọrun to da gbogbo nnkan laye ati ọrun.
Titi wọn fi pari eto adura naa ni Gomina Abiọdun fi duro, to si ba wọn ṣe oore ọfẹ.
Yatọ si Gomina Abiọdun, bẹẹ ni Gomina ipinlẹ Ekoo, Babajide Sanwo-Olu naa ko gbẹyin nibi eto adura naa.
No comments:
Post a Comment