Lọjọ Aiku Sande ana ni ọkan ara awọn gbajugba oṣere-binrin nni, Ayọ Adesanya ṣayẹyẹ ọjọ ibi aadọta ọdun loke eepẹ, to si jẹ kawọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye, paapaa lori ayelujara mọ pe kii ṣe agbara oun, bi o ṣe ifẹ Ọlọrun.
Ayọ Adesanya sọ pe anfaani nla lo jẹ foun lati pe aadọta loke eepẹ nitori pe iru anfaani bẹẹ ko wọpọ, toun si n dupẹ fun awọn nnkan rere ti Ẹlẹda ti ṣe foun ati eyi ti yoo tun ṣe.
Titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan lawọn eeyan ṣi n fi atẹjiṣẹ orirre ranṣẹ si Ayọ Adesanya.
No comments:
Post a Comment