GBAJÚMỌ̀ ONÍRÒYÌN DI Ọ̀GÁ ÀGBÀ SÍFÚ DIFENSI NIPINLẸ ÒGÙN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 5, 2019

GBAJÚMỌ̀ ONÍRÒYÌN DI Ọ̀GÁ ÀGBÀ SÍFÚ DIFENSI NIPINLẸ ÒGÙN

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ọkan pataki lara awọn akọroyin tẹlẹri nipinlẹ Ọṣun, Hammẹd Abọdunrin ti di ọga agba ajọ Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ogun bayii, to si ti bẹrẹ iṣẹ.

Opin ọsẹ to kọja yi la gbọ pe Hammẹd Abọdunrin to ti figba kan ri jẹ akọwe ẹgbẹ oniroyin nipinlẹ Ọṣun lẹẹmeji ọtọọtọ, ko too gba iṣẹ Sifu Difẹnsi, to si jẹ pe ko pẹ to fi di ọga lẹnu iṣẹ naa.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ajọ Sifu Difẹnsi naa, Ọgbẹni Dyke Ogbonnaya ṣe fi to wa leti, a gbọ pe bi Kọmanda Hammẹd Abọdunrin ṣe de ipinlẹ Ogun, ọfiisi olori awọn oṣiṣẹ gomina lo gba lọ lati lọọ ṣabẹwo sii ni nnkan bi aago marun ku iṣeju mẹẹdogun irọlẹ ọjọ keji oṣu yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI