Lati le jẹ ki eto aabo to peregede jọba nipinlẹ Ogun ati agbegbe ẹ, Gomina ipinlẹ naa, Ọmọba Dapọ Abiọdun ti pawọwa fawọn araalu, paapaa awọn Lanlọọdu ati agbanisile (Caretaker) pe ki wọn rii daju wọn n mọ iru ẹni ti wọn ba n gba sile wọn, nitori pe bi wọn ko ba ṣe ofintoto lati mọ iru ẹni ti wọn n gbe ile fun yoo ran wọn lọ sẹwọn apapandodo.
Lonii ni Gomina Abiọdun ṣe ikilọ naa lasiko to n bawọn oniroyin sọrọ ni ọfiisi ẹ to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta latari tawọn Pasitọ Ṣọọṣi Ridiimu ti Baba Adeboye tawọn ajinigbe ji gbe lọsẹ to kọja, ṣugbọn tawọn ọlọpaa ti ri wọn gba pada.
Nibẹ ni Gomina Dapọ
Abiọdun ti jẹ ko di mimọ pe igbesẹ ti bẹrẹ lati maa lọọ ṣewadi gbogbo awọn to n gbe nipinlẹ Ogun, lati le mọ iru eeyan ti wọn jẹ, to si ni asiko re fawọn lanlọọdu to ba gba ọdaran sile lati tete le wọn jade ki aṣiri too tu.
Yatọ si pe lalọọdu tabi olugbanisile to ba gba ọdaran sile lọ sẹwọn, iru ile bẹẹ yoo tun pada di wiwo, nitori pe eto aabo to lọọrin nijọba ti ṣeto silẹ bayii, to si ni aabo ẹmi ati dukia awọn araalu lo jẹ oun atijọba oun logun.
Bakan naa lo tun fi ye awọn eeyan pe igbesẹ lati ṣe fiflọlẹ eto aabo tawọn eeyan mọ si Security Trust Fund, pẹlu agbekalẹ ofin
siwaju awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lati jiroro lori idajọ fawọn ọdaran tọwọ ba
tẹ.
Siwaju sii lo gbe oṣuba kare fun Aarẹ orilẹede yi, Ọgagun Muhammadu Buhari
lori bo ṣe tete pese awọn ohun elo lati fi gbogun ti awọn ọdaran nipinlẹ Ogun.
Bẹẹ lo tun fi ẹmi imoore rẹ han si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fun iṣẹ takuntakun ti
wọn ṣe lati le ri awọn eeyan marun un naa pada lagbegbe Ọgbẹrẹ si Sagamu, iyẹn lopopona
marosẹ Benin si Ekoo.
No comments:
Post a Comment