ẸSIN AJOJI LO N ṢAKOBA FUN WA NI NAIJIRIA – DỌKITỌ ṢOYỌYE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 12, 2019

ẸSIN AJOJI LO N ṢAKOBA FUN WA NI NAIJIRIA – DỌKITỌ ṢOYỌYE

Ọjọgbọn ninu iṣegun ibilẹ ni Dọkitọ Samson Ṣoyọye jẹ lorilẹ-ede Naijiria ati lagbaye, ati paapaa nilẹ Adulawọ. Oludasilẹ ile-ẹkọ imọ iṣegun ibilẹ, iyẹn African College of Traditional Medicine to fikalẹ sagbegbe Wasinmi nijọba ibilẹ Ewekoro, ipinlẹ Ogun ni pẹluu. Bakan naa ọkan pataki lara awọn ti ko fẹ ki aṣa ati iṣe Yoruba parun ni, ti ko si ni i fi igba kan bo ekeji.

Laipẹ yi Dọkitọ Ṣoyọye b’AWIKONKO sọrọ lori ọwọ tawọn ọmọ Yoruba fi n mu aṣa ati ẹsin abalaye wọn, to si jẹ ko di mimọ pe ko si nnkan to buru ninu aṣa ati iṣe ile Adulawọ, paapaa ti ilẹ Yoruba. Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe ẹtanjẹ lasan lawọn ọmọ Adulawọ fi n lu ara wọn ni jibiti, to si tun jẹ ko di mimọ pe ẹsin ajoji lo n da awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria laamu, kii ṣe nnkan min.

Yatọ si eyi, Dọkitọ Ṣoyọye sọ diẹ nipa itan igbesi aye rẹ fun AWIKONKO, bẹẹ lo tun sọ idi pataki to fi da ile-ẹkọ iṣegun ibilẹ silẹ ati ọwọ tijọba fi mu ile-ẹkọ naa. Ẹ jẹ igbadun ifọrọwerọ naa:

ORUKỌ MI ATI BI MO ṢE JẸ
Orukọ mi ni Oloye Oniṣegun Samsom Ṣoyọye. Oniṣegun ibilẹ ni mi, mi o kii ṣe babalawo, ṣugbọn ohunkohun ti a le fi ewe ati egbo ṣe lọna ibilẹ, eyi ti imọ ijinlẹ sayẹnsi fidi ẹ mulẹ lati fi wo eeyan san, ti a si tun le fi gba eeyan kalẹ ninu idaamu ati iṣoro ni mo mọ nipa ẹ dujuduju. Bo tilẹ jẹ pe Ọlọrun funra rẹ lo n gba eeyan kalẹ ninu iṣoro, ṣugbọn eeyan lo maa ran an gẹgẹ bi angẹli.

IGBA TI MO TI WA LẸNU IṢẸ YI
Mo le sọ pe ajogunba ni, mo si tun le sọ pe ajogunba kọ, nitori pe mi o duro kọ iṣẹ naa lọdọ baba mi. Wọn maa n kọ iṣegun ibilẹ ni. Bi eeyan ko ba kọ iṣegun ibilẹ lọna igbalode, a jẹ pe awọn aṣiṣe tawọn baba wa maa n ṣe nigba aye wọn naa lawọn ti ko ba ko iṣẹ yi lọna igbalode naa ma maa ṣe lọ. Ajogun ba ni, ṣugbọn a tun ti ti ọlaju bọ eyi ti a jogun ba. A ti gbe lọna ti imọ ijinlẹ sayẹnsi la kalẹ pe ka maa ṣe. Bi mo ma bu kere, ọgbọn ọdun re e ti mo ti wa lẹnu ẹ.

IDI TI MO FI YA SIDI IṢẸ ONIṢEGUN IBILẸ
Ẹnikẹni to ba fẹ wo eeyan san gbọdọ sunmọ awọn ti wọn ni imọ ijinlẹ ati oye ninu bi wọn ṣe n wo eeyan san, ko ba jẹ pẹ ṣinbi ijẹun ni wọn yoo fi gbe aisan wa, ti wọn yoo si fi baafu ru aisan naa pada sile wọn. Wọn maa n ko iṣẹ yi. Iṣẹ to wu mi lati ṣe ni kekere, bo tilẹ jẹ pe erongba eeyan yatọ si ipinu Ọlọrun aṣẹda. Loootọ, Dọkitọ Oyinbo lo wun mi lati ṣe nigba ti mo ṣi kere, ṣugbọn Ọlọrun mọ bo ṣe n ṣeto ẹ to fi mu mi ya sidi iṣegun ibilẹ. Mi o si kabamọ pe mo n ṣe iṣẹ yi.

IYATỌ TO WA LAARIN IṢẸ IṢEGUN IBILẸ ATI BABALAWO
Babalawo jẹ awọn ti wọn yẹ ifa wo, awọn ti wọn n bawọn Irunmalẹ sọrọ, eyi tawọn Oloyinbo n pe ni Traditionalists ati Oracle Consultants, ṣugbọn awọn Oniṣegun ibilẹ ti wọn n wo eeyan san lawọn Oloyinbo n pe ni Herbalists, ẹni to ni imọ ijinlẹ ati oye lati lo ewe ati egbo pẹluu awọn alumọọni ti Ọlọrun sa pẹluu wọn fun iwosan awọn eeyan. Awọn babalawo n wo igba ati ọjọ, wọn si le sọ fun un yin pe ajẹ kan lo n da ẹni kan laamu, ṣugbọn mo fẹ ẹ sọ fun un yin pe ko si nnkan to kan Oniṣegun ibilẹ pẹluu gbogbo iyẹn. Babalawo maa n rubọ, ṣugbọn etutu ni Oniṣegun ibilẹ maa n ṣe. Egboogi ni Oniṣegun ibilẹ n ṣe, tawọn Babalawo si n ṣe oogun. Egboogi yatọ si oogun, oogun si yatọ si egboogi. Ẹbọ riru yatọ si etutu, bẹẹ bi etutu yatọ si ẹbọ.

IDI TI MO FI RONU LATI DA ILE-ẸKỌ SILẸ
Ile-ẹkọ ti mo da silẹ, iyẹn African College of Traditiona Medicine kii ṣe imọ ti awọn baba fi kọ wa. Ilana ti awọn Oloyinbo ni mo fi da a silẹ, ẹnikẹni to ba fẹẹ ṣe iwosan lọna ti Oloyinbo, o gbọdọ kọ bi oloyinbo ṣe n ṣe iwosan ti ibilẹ ni. Awọn ti wọn n ṣe iwosan ibilẹ pọ rẹpẹtẹ niluu Oyinbo, o si yatọ si bi wọn ṣe n ṣe nibi. Ẹnikẹni to ba fẹ ṣe iṣegun ibilẹ lọna ti Oloyinbo gbọdọ kọ ọ, bawọn Oloyinbo ṣe n ṣe iṣegun ibilẹ ti wọn niyẹn. Fun apẹẹrẹ, bi ẹ ba ri awọn ẹgboogi ti a ti ṣe silẹ, eyi to le lo ọdun mẹta ati ju bẹẹ lọ wa nibẹ, bi ẹ ba si ṣe fi silẹ lonii naa lẹ maa ba nibẹ lẹyin ọdun mẹta, ko nii si iyatọ kankan, idi ni pe ilana ti igbalode tawọn Oloyinbo fi n ṣe egbooogi ti wọn la fi ṣe wọn sibẹ. A si maa n kọ ọ ni, beeyan ko ba kọ ọ, o n tan ara rẹ jẹ ni. Lati le ma jẹ ki aṣa, iṣe ati iṣegun ibilẹ wa parun lo fa a, ti mo fi da ile-ẹkọ African College of Traditional Medicine silẹ, paapaa fawọn to ba mọ nipa iṣegun oyinbo ati agbẹbi.

BI IJỌBA ṢE T’ẸWỌ GBA ILE-ẸKỌ YII
Ijọba tẹwọ gba ile-ẹkọ yi lọdun marun un sẹyin, ṣugbọn tori pe mo bẹru ofin ni ko jẹ ki n fi si ojuṣe ayafi igba ti ijọba fi ontẹ luu. Igba ti ajọ iforokọ silẹ ileeṣẹ ati okoowo lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn Corporate Affairs Commission gbe iwe aṣẹ le mi lọwọ, ẹyin ẹ ni mo ṣẹṣẹ lọ si ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ eto ẹkọ, iyẹn Ministry of Education lati lọ fi to wọn leti. Nigba ti a kọkọ de bẹ, esi ti wọn kọkọ fun wa ni pe awọn ko le dari ẹ nitori pe kii ṣe nnkan tawọn mọ nipa rẹ. Eyi lo tun mu wa fi kun irin ẹsẹ wa, to di pe Gomina igba naa, Ọtunba Gbenga Daniel da sii, Gomina Daniel lo jẹ ko ye wọn funra rẹ pe wọn n kọ iṣegun ati iwosan ibilẹ ni, nitori naa ki wọn fi orukọ wa silẹ lọdọ ijọba ati labẹ ofin.

Lorilẹ-ede Naijiria lonii, ile ẹkọ meji pere lo jẹ ile-ẹkọ iṣegun ibilẹ, akọkọ ni African College of Traditional Medicine, ekeji ni Royal College of Traditiona Medicine. Ọṣẹ Itura lo da Royal College of Traditional Medicine silẹ niluu Ṣagamu, ṣugbọn latigba ti Ọṣẹ Itura ti papoda, ni ile-ẹkọ naa ko ti gberi mọ, nitori pe awọn ọmọ to fi silẹ ko mọ riri nnkan ti baba fi silẹ lọ. Ti wa yi nikan lo ku, ṣugbọn awọn min in ti ẹ ba tun n gbọ orukọ wọn, kii ṣe iṣegun ibilẹ ni wọn n ṣe, bi ko ṣe pe wọn kan n fara pẹ orukọ iṣegun ibilẹ ti wa ni.

Ijọba ko da sil ile-ẹkọ yi rara, ko da a, awọn ileeṣẹ, ajọ ati ile-ẹkọ to lorukọ daadaa, ijọba ko da si wọn rara, bawo wa ni ti wa ṣe fẹ ẹ jẹ, wọn ko ti ẹ fẹ mọ nnkan ti a n ṣe nibẹ. Nigba ti a ti ẹ tun ṣabẹwo si ileeṣẹ ijọba ti Iṣegun, iyẹn Ministry of Health lati le fọwọsowọpọ pẹluu wa, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn sọ pe awọn ko le da si nnkan tawọn ko mọ nipa rẹ, nitori pe awọn ko kọ iṣẹ de bẹ, nitori naa, o ṣoro lati da si.

AṢA WA KO LE PARUN, AYAFI BI A BA FẸ KO PARUN
Ki ẹni to ba n sọ pe aṣa ati iṣe wa maa parun ko ẹru rẹ kuro lọ siluu Oyinbo. Nnkan ti ko ye wa ni pe aṣa ati iṣe awọn Oyinbo ni a ko owo wa ra lonii, nitori pe ohun ti ni wọn fi n mu idagbasoke ba ilu wọn, to si jẹ pe ko si eyi to dara to eyi ti a ni nilẹ Yoruba. Olori wa kan lorilẹ-ede yi, ẹni ti mi o ni fẹ ẹ darukọ rẹ, bi nnkan kan ba gun un lara lasan, o ti sare gbe oke-okun lọ lati lọọ ṣayẹwo, aṣa ati iṣe ti wọn lo ko owo Naijiria lọ wo lọhun yẹn. Awọn kan ti n gba China ati India lọ, to si jẹ pe ewe ati egbo ti wọn ni wọn n lo fun wọn lọhun, ti awa naa si ni tiwa nibi. Ilana tawọn ara China ati India n lo lati fi ṣe egboogi wọn la fi n kọ awọn akẹkọọ wa, ti a si n fi si ojuṣe, ti wọn si n ri bẹ ẹ. Ko da a, awọn aisan ti wọn ba ti kọ kaakiri ileewosan la n fi opin si lọdọ wa nibi, lai si wi pe bo ya wọn n rubọ pẹluu ẹ.

Lori wi pe wọn n rubọ pẹluu iṣegun, ẹ ma jẹ ka tan ara wa jẹ, awọn Oyinbo gan an rubọ pẹluu awọn nnkan ti wọn n ṣe. Ko si ẹlẹbọ to ju China ati India ati Brazil lọ lagbaye, ṣe orilẹ-ede Naijiria lawọn yẹn wa ni. Ẹsin ajeji lo n da wa laamu laamu lorilẹ-ede Naijiria, ki i ṣe nnkan min in. Ẹsin ati iṣe awọn Oyinbo lo n da wa laamu lorilẹ-ede Naijiria. Ọlọrun to da ewe ati egbo ninu Bibeli ti a n gbe kaakiri, paapaa iwe Esikiẹli ori kẹtadinlaadọta ẹsẹ kejila (Ezekiel 47:12) sọ pe “Ati lẹba odo ni eti rẹ, ni iha ihin ati ni iha ọhun, ni gbogbo igi jijẹ yi o hu, ti ewe rẹ ki yio rọ, ti eso rẹ ki yio si run: yio maa so eso titun rẹ li oṣu rẹ, nitori omi wọn lati ibi mimọ ni nwọn ti ntu jade: eso rẹ yi o si jẹ fun jijẹ, ati awọn ewe rẹ fun imunilarada.”. Ka ti ẹ wa sọ pe wọn ko fara mọ Majẹmu lailai mọ, ka bọ sori Majẹmu titun, iwe Ifihan ori kejilelogun ẹsẹ keji (Revelations 22:2) naa sọ pe “Li aarin igboro rẹ, ati niha ikini keji odo na, ni igi iye gbe wa, ti ima so oniruuru eso mejila, a si maa so eso rẹ li oṣooṣu: ewe igi na si ni fun mimu awọn orilẹ-ede larada.”

Bi ẹ ba si wo o, iṣẹ ọjọ kẹta ni ewe ati egbo jẹ nigba ti Ọlọrun da ọrun ati aye, ko to o ṣẹṣẹ da eniyan lọjọ kẹfa lati maa lo awọn nnkan wọnyi fun ajinde ara. A wa tori ẹsin tawọn alawọ funfun gbe wa fun wa, a pa ẹsin abalaye wa ti, a n jẹ ki aṣa wa parun mọ wa loju. Aimọkan lo n da wa laamu. Bi ẹ ba wo awọn aṣaaju ẹsin wa, ti iwe Mika ori keje ẹsẹ keji (Micha 7:2) fidi ẹ mulẹ pe “Oninurere ti run kuro li aiye: ko si si olotitọ kan ninu enia: gbogbo wọn ba fun ẹjẹ, olukuluku wọn n fi awọn dẹ arakunrin rẹ.” Ẹṣe karun rẹ tun sọ pe “Ẹ ma gba ọrẹ kan gbọ, ẹ ma si gbẹkẹle amọna kan: pa ilẹkun ẹnu rẹ mọ fun ẹniti o sun ni ookan-aiya rẹ.” Tani awọn amọna ti bibeli n sọ yi, ṣebi awọn to fun ara wọn lorukọ bii Pasitọ, Rẹfunrẹndi ati Wolii ni. Bi bibeli ṣe tobi to yẹ, ẹ ko le ri ibi ti wọn kọ Pasitọ si ninu ẹ, awọn ni wọn fun ara wọn ni oye yẹn ni, kii ṣe oye bibeli, ki wa ni wọn n jẹ orukọ naa fun un?

Wọn a lọ si ile-ẹkọ Bibeli, bi wọn ba jade, wọn a fun ara wọn ni orukọ, bẹẹ na lo jẹ pe awọn to n jade nibi n gba oye Ọjọgbọn, ko si iyatọ. Ọlọrun kọ lo paṣẹ pe ki wọn maa jẹ Pasitọ, to si jẹ pe igba ti wọn de ni wọn wa n pa aṣa ati ẹsin wa run un. Epo igi ṣaa ni wọn fi ṣe Bibeli ti a gbe kiri, a ko si le bu ẹnu atẹ lu awọn nnkan ti a n lo fi ṣe egboogi ibilẹ tori pe Ọlọrun lo da wọn. Awo yatọ si iṣẹgun.

AWỌN TI A N GBA LATI KẸKỌỌ
Ẹni to ba fẹẹ wa sile-ẹkọ wa gbọdọ ni imọ iwe, bi ko tiẹ pọ, o gbọdọ jade iwe ile-ẹkọ alakọbẹrẹ, iyẹn pamari six. Ẹni naa si gbọdọ mọ iwe kikọ ati kika dujuduju. Ni ti ọjọ ori, ẹni to kere ju ti a n gba ko gbọdọ din lọmọdun mẹtadinlogun (17years), ṣugbọn ti a n ri to pọ ju lawọn dọkitọ Oloyinbo ti wọn tun fẹ ẹ ni imọ kun imọ ati oye kun oye, ti wọn si n jẹ anfaani alailẹgbẹ. Wọn n pe awọn kan ni auxiliary nurse, ti wọn n sa si abẹ ẹgbẹ ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Traditional Birth Attendant, abẹrẹ nikan ni wọn n gun, ti wọn si n gbe omi soke fawọn alaisan. Ko ma ba a si iru ẹ mọ la ṣe n sọ fun wọn pe ki wọn wa kọ iṣẹ iwosan ati igbẹbi lọna ibilẹ gangan, iyẹn Tradtional Birth Attendant pọnbele lai lo oogun Oyinbo kankan. Paapaa awọn ti wọn fẹ ẹ mọ nipa bi a ti n po ewe ati egbo papọ mọ ara wọn lọna ibilẹ, to si maa ṣiṣẹ fun iwosan. Ko sẹni ti ko le wa sibi lati kẹkọọ, awọn dọkitọ Oloyinbo gan an ni wọn nilo imọ yi ju, to si jẹ pe a ti n ri diẹ-diẹ lara wọn.

OYE TI A N FUN AWỌN AKẸKỌỌ JADE
Gbogbo oye tawọn akẹkọọ n gba ninu ẹkọ iṣegun Oloyinbo naa ni wọn n gba nibi, bo tilẹ jẹ pe a ko tii dagba to tawọn ile-ẹkọ nla, idi ni yii to fi jẹ pe awọn to ṣi n kẹkọọ jade bayii, iwe ẹri imọ bii Certificate of Knowledge, Basic Knowledge of General Traditional Medicine, Advanced Course on Basic Knowledge of Traditional Medicine. Lai pẹ, a maa bẹrẹ Diploma ati Certificate Course ati Professional Courses.

AWỌN OHUN IJA ILẸ YORUBA ṢI WA BII TI ATIJỌ
Ijọba wa lorilẹ-ede Naijiria, mo le fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe ọbọ ni wọn. Awọn baba wa laye atijọ ko ni bọmbu nitori pe wọn n dojukọ awọn ẹranko buburu, wọn si n pa wọn lai yinbọn. Awọn nnkan bayii ṣi wa nibi ti wọn wa, wọn ko tii tan nilẹ, ṣugbọn tori ajẹbanu, ati iwa ole to ti fi ba Naijiria jẹ ni ko jẹ ki wọn ya sidi ẹ. Tori owo ti wọn fẹẹ ji gbe ni wọn ṣe n gbe obitibiti owo to le ni biliọnu lọọ ra awọn nnkan ogun loke okun, sibẹ naa, ko tii si ogu ti a le sọ pe wọn ti ṣẹ patapata. Ẹ jẹ ki wọn pe awọn oniṣegun ibilẹ ati awọn babalawo jọ, ki wọn kan fun wọn ni miliọnu lọna ọgọrun (100milion) naira pere lati dide. Ta lo n jẹ Boko Haram, abi ta lo n jẹ Fulani Darandaran apaniyan, gbogbo wọn pata ni wọn yoo rin jinna rau-rau.

Ko digba ti wọn n yinbọn abi bọmbu ki wọn to o ṣe wọn. Bakan ṣaa lawọn baba wa ṣe ṣẹgun Adubi, bakan ni wọn ṣe ṣẹgun Itila, bakan ni wọn ṣe ṣẹgun agbaye kinni ati ekeji (World War 1) lai gbe bọmbu tabi ibọn lọọ jagun. Yoruba ni nnkan lọwọ, ilẹ alawọn funfun naa ni nnkan lọwọ, ṣugbọn ijọba wa ko faaye gba a, ẹni to ba n lo awọn nnkan wọnyi, ẹwọn lo maa pẹ si i. Bi apẹẹrẹ, bi eeyan ba de igbadi lopopona, ti ọwọ ọlọpaa ba tẹ ẹ, ẹsun ajinigbe, adigunjale tabi apaayan ni wọn a fi kan an. Awọn ọlọpaa ti a si n sọ yi, adigunjale ati apaayan to gba iwe ẹri ni wọn. Won a gbe ibọn dani lopopona, owo ti wọn n gba lọwọ onimọto lẹgbẹ ọna, ṣe pẹluu idunnu lawọn onimọto fi n fun wọn ni, ṣebi tori ibọn ti wọn gbe dani ni. Kinni itunmọ ‘ole’, nnkan teeyan ba fi tipatipa gba lọwọ ẹnikẹji ni wọn n pe bẹẹ. Ati ẹni to ji ẹran iya ẹ jẹ ninu iṣasun pẹluu ẹni to lọ ja owo gba lopopona, ko si iyatọ kankan laarin awọn mejeeji bi ko ṣe pe ole ni wọn.

AMỌRAN MI
Bi mo ṣe wa yi, adura ti mo n gba ni pe ki apa kan lara aṣa Yoruba parun, mi o le gbadura taara si Ọlọrun pe ki aṣa wa parun, ṣugbọn mo n fẹ ki apa kan ninu aṣa Yoruba parun. Ọlọrun to da wa sọ pe iwọ ko gbọdọ ni Ọlọrun miiran pẹluu mi, nnkan to tunmọ si ni pe a ko gbọdọ ṣe ẹbọ. O tun sọ pe iwọ ko gbọdọ ya erekere fun ara rẹ. Nnkan to n sọ ni pe a ko tun gbọdọ foribalẹ fun nnkan miiran, bi ko ṣe oun Ọlọrun. Ti iru aṣa bayii ba le parun, ko tete parun. Ṣugbọn aṣa wa to ba ifẹ Ọlọrun mu, mo n bẹbẹ si Ọlọrun atawọn ọmọ Yoruba lati ma jẹ ko parun mọ wa loju, bi ko ṣe pe ko tubọ maa gbilẹ sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI