Titi dasiko ti a kọ iroyin yi tan lọrọ ẹranko abami kan ti wọn loo wọ adugbo kan ti wọn n pe ni Abaji niluu Abuja, to si fa agbo Ileya ya pẹrẹpẹrẹ ṣi n jẹ kayeefi, paapaa fun awọn ara agbegbe naa.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ oru ana ni wọn sọ pe ẹranko ti ẹnikẹni ko tii le ṣapejuwe rẹ dasiko yi wọle, to si ki awọn agbo to wa lagbegbe naa mọle, paapaa nigba ti wọn loo tun ki agbo Ọnọrebu kan to gbajumọ daadaa, iyẹn Ọnọrebu Kamal ya pẹrẹpẹrẹ.
Iṣẹlẹ naa ko dun mọ awọn ti wọn ti n gbero lati fi ẹran agbo wọn ṣe ayẹyẹ ọdun Ileya ninu latari bi wọn ṣe ni ẹranko buruku naa fawọn ya kọja lilo, depodepo fun ọdun Ileya.
No comments:
Post a Comment