Ṣe lọpọ awọn eeyan kawọ mọri nipinlẹ Ẹdo laipẹ yi nigba ti ileeṣẹ aabo ti ọtẹlẹmuyẹ (DSS) foju awọn gendekunrin meji kan ti wọn ni wọn ko niṣe meji ju jibiti ori ayelujara, iyẹn Yahoo-Yahoo lọ, to si jẹ pe orukọ Iyawo Aarẹ orilẹede yi, Aishat Buhari ati gbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ni wọn fi n lu awọn eeyan ni jibiti owo lori ayeluajra.
Awọn mejeeji ni Amos Ehis Asuelimen ti wọn lọmọ ọgbọn ọdun ni, to si tun jẹ akẹkọọ fasiti Ambrose Alli lẹka eto okoowo (Business Administration ati Kelvin Godwin Ogashi toun jẹ ọmọdun mejidinlogun.
Igbakeji ọga agba,
Galadima Byange lo foju awọn ọdaran yi han fawọn oniroyin l'Ọjọbọ ana nipinlẹ Ẹdo.
A gbọ pe ayederu orukọ Ọṣinbajo ati Aishat Buhari lawọn mejeeji n lo lori ikanni ayelujara ti Facebook, ti wọn si lawọn fẹ maa ya awọn eeyan lowo, ati pe awọn ti wọn ba fẹẹ ran lọwọ lati ya lowo gbọdọ kọkọ fi kaadi ipe ibanisọrọ ranṣẹ, ta a si gbọ pe ko din leeyan marun un ti wọn ti gba owo lọwọ wọn.
AWIKONKO gbọ pe awọn mejeeji ko ni pẹ ẹ foju bale ẹjọ.
No comments:
Post a Comment