Ẹ WA A GBỌ NNKAN TI MIKE BAMILOYE SỌ NIPA AWỌN OLORIN TAKASUFE ATAWỌN OṢERE TIATA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, August 19, 2019

Ẹ WA A GBỌ NNKAN TI MIKE BAMILOYE SỌ NIPA AWỌN OLORIN TAKASUFE ATAWỌN OṢERE TIATA

Gbajugbaja ojiṣẹ Ọlọrun nni, Mike Bimiloye, ẹni to n lo ipe ati ẹbun rẹ fi ṣe fiimu jade sita ti parọwa fawọn olorin takasufe atawọn oṣere tiata kaakiri agbaye, paapaa lorilẹ-ede Naijiria wi pe ki wọn kọ eṣu ati iṣẹ ọwọ rẹ silẹ, ki wọn si pada sọdọ Ọlọrun to fun l'ẹbun.

Mike Bamiloye to tun jẹ ilu mọn ọn ka oṣere tiata ati oludasilẹ Mount Zion Films lo parọwa yi lori ikanni ayelujara rẹ laipẹ yi pe bawo ni eeyan yoo ṣe gba ẹbun lọwọ Ọlọrun, ti yoo si maa lo o fun eṣu, eyi ko bojumu rara, gẹgẹ bo ṣe sọ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Gbogbo ẹyin ti ẹ ni ẹbun nidi iṣẹ orin, tiata, ati lilo ohun elo orin, ti Ọlórun ti gbe e yin dide lati inu ṣọọṣi, wi pe ki ẹ le wulo fun oun, Ṣugbọn ẹ ti pa Ọlọrun to gbe e yin dide ti sẹgbẹ kan, ẹ si ti n kọrin nile igbafẹ ati kilọọbu kaakiri.

"Mo bẹ yin pe ki ẹ pada si orisun yin. Bawo lẹ ṣe maa gba ẹbun lọwọ Ọlọrun, ti ẹ si maa gbe le eṣu lọwọ?"

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI