Bi ijọba ipinlẹ Ogun ko ba tete gbe igbesẹ lati ko awọn ọtẹlẹmuyẹ jade sita lati maa ṣọ awọn dukia ipinlẹ naa, afaimọ ki wọn ma ji gbogbo ẹ ko mọ wọn loju tan, paapaa bi wọn ṣe sọ pe awọn ti wọn n ṣa irin kaakiri, iyẹn bola-bola ti fẹẹ ge awọn irin afara Lafẹnwa niluu Abẹokuta tan.
Gẹgẹ bi awọn to firoyin naa to AWIKONKO leti ṣe sọ, wọn loo ti le loṣu meloo kan sẹyin lawọn bola-bola naa ti wọn sọ pe Hausa ni wọn ti n ge irin ti wọn ṣe sẹgbẹ afara naa lati ma jẹ kawọn eeyan jabọ sinu odo.
A gbọ pe diẹ-diẹ lawọn bola-bola naa n ge awọn irin yi, ti ẹnikẹni ko si fura, eyi ti wọn lo ṣe e ṣe kawọn eeyan to n gba ori afara naa kọja jabọ sinu odo lojiji.
Diẹ re e lara awọn irin ti wọn ge naa.
No comments:
Post a Comment