Gomina ana nipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ti sọ pe owo ti ko din ni biliọnu mejidinlogun naira, iyẹn N18.3b loun fi silẹ ninu apo owo ijọba ipinlẹ naa koun too gbe ijọba silẹ loṣu karun ọdun ọdun yi.
Kọmiṣana ana fọrọ eto iṣuna owo, Ọgbẹni Adewale Ọshinọwọ lo jẹ ko di mimọ fawọn araalu lọjọ Aje Mọnde ana pe Sẹnetọ Ibikunle Amosun fi owo naa silẹ lati le jẹ ki ijọba rọrun fun Gomina Dapọ Abiọdun.
Ọshinọwọ sọ pe iyalẹnu lo jẹ nigba toun gbọ pe Gomina Abiọdun sọ pe ko si owo kankan inu apo owo ipinlẹ Ogun, to si tun fi to gbogbo aye leti pe ṣe loun lọọ ya biliọnu meje naira toun fi san owo oṣu karun un fawọn oṣiṣẹ, eyi to sọ pe irọ ti ko si ọtitọ ni.
O jẹ ko ko di mimọ pe lara awọn owo tijọba ana fi silẹ ni biliọnu mẹfa din lẹgbẹrun lọna ọọdunrun (N5.7bn) naira lati apo owo ijọba apapọ, biliọnu meji aabọ (N2.5bn) naira lati tawọn ẹka ileeṣẹ ijọba (Ministries Departments and Agencies), ati biliọnu mẹwaa aabọ (N10.6bn) naira to jẹ gẹgẹ bi owo to n wọle sapo ijọba, iyẹn owo to pe ni Pay As You
Earn.
Bo tilẹ jẹ pe Gomina Abiọdun ko tii tako ọrọ naa titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, ohun tawọn kan n sọ ni pe ko si otitọ kankan ninu ọrọ ti Ọṣhinọwọ sọ, to si n wa awawi lati ṣi awọn araalu lọkan nipa ijọba Gomina Dapọ Abiọdun.
Bẹẹ lawọn kan n gba ijọba lamọnran pe kawọn naa jade tako ọrọ ọhun ko too pẹ ju fawọn araalu lati mọ.
No comments:
Post a Comment