Gbogbo eto la gbọ pe o ti to bayii fun ẹgbẹ alaabo So Safe Corps nipinlẹ Ogun, eyi ti Ọgbẹni Olusọji Ganzallo jẹ Kọmanda wọn lati wọ iya ija pẹluu awọn ọdaran kaakiri ipinlẹ naa, paapaa bi wọn tun ṣe tọwọ bọwe adehun pẹluu awọn ileeṣẹ eleto aabo yooku kaakiri.
Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ, wọn a mọ daju pe bi awọn asiko ayẹyẹ gbogboogbo bayii ba ti n waye lawọn ọdaran bii ọmọ ẹgbẹ okunkun, adigunjale maa n gbero lati ṣọṣẹ wọn, eyi ti wọn loo le da alaafia ilu laamu.
Eyi gan an la gbọ pe o mu ẹgbẹ alaabo So Safe Corps pinu lati ṣiṣẹ papọ pẹluu awọn ileeṣẹ eleto aabo yooku kaakiri ipinlẹ Ogun, ki eto aabo le tubọ kẹsẹjare lasiko ati lẹyin ọdun Ileya.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Mọruf Yusuf ṣe ṣalaye fun wa, o sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko ṣẹṣẹ maa tọwọ bọwe adehun pẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo, ṣugbọn, eyi tawọn tuntun ṣẹṣẹ ṣe yii yatọ patapata sawọn eyi tawọn ti n ṣe tẹlẹ, nitori pe iṣe wọn ti yatọ si tigba tawọn ṣi n jẹ Fijilante.
Mọruf sọ pe gbogbo awọn ahere kaakiri awọn adugbo lawọn ti ṣeto awọn ọmọ ẹgbẹ wọn si lati maa ṣọ ẹnikẹni to ba fẹẹ wọ ipinlẹ Ogun wa a ṣiṣẹ ibi, lati le tete koju wọn, ati pe awọn ko ni i gba iwa ọdaran kankan laaye lasiko ati lẹyin ọdun Ileya, tori pe ojuṣe wọn ni lati daabo bo awọn araalu.
Mọruf sọ pe gbogbo awọn ahere kaakiri awọn adugbo lawọn ti ṣeto awọn ọmọ ẹgbẹ wọn si lati maa ṣọ ẹnikẹni to ba fẹẹ wọ ipinlẹ Ogun wa a ṣiṣẹ ibi, lati le tete koju wọn, ati pe awọn ko ni i gba iwa ọdaran kankan laaye lasiko ati lẹyin ọdun Ileya, tori pe ojuṣe wọn ni lati daabo bo awọn araalu.
O wa fọkan awọn araalu balẹ pe ki wọn ma ṣe foya tabi bẹru, nitori pe awọn ti wa ni igbaradi lati daabo bo ẹmi ati dukia wọn, ati pe asiko naa re e ti wọn le sun, ki wọn họn oorun.
Bẹẹ lo rọ awọn araalu pe ki wọn ma ṣe pa ẹnu wọn mọ lati tete fi awọn ọdaran ti wọn ba kẹfiri lagbegbe wọn to wọn leti, eyi to sọ pe o le tubọ mu iṣẹ rọrun fun wọn.
Bakan naa lo tun sọ pe awọn ti ṣeto awọn nọmba ẹrọ ibanisọrọ meji ọtọọtọ tawọn araale le maa fi iṣẹlẹ to ba n lọ to wọn leti. Awọn nọmba naa ni:
09069392064 ati 08035479930.
No comments:
Post a Comment