Gbogbo ilu Makurdi, nipinlẹ Benue lo fẹẹ le daru laarọ oni nigba ti wọn ba oku ọmọge arẹwa kan ta a ko tii mọ orukọ rẹ dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan ninu igbo kan to wa niwaju ṣọọṣi ti wọn pe ni Grace Tower.
Ohun ta a gbọ ni pe awọn gendekunrin kan ni wọn fipa wọ ọdọmọbinrin naa, ti wọn si ko ibasun fun lẹyọ-kọọkan, titi to fi jade laye.
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni wọn ja ọmọbinrin naa sihoho ọmọlaubi, ti wọn si fi aṣọ dii lẹnu pa, ki wọn too bẹrẹ sii fi kinni abẹ wọn dana si ọmọge arẹwa naa labẹ.
Igba ti wọn ni agbara ọmọbinrin yi ko fẹẹ gbe mọ, lẹyin to ti bẹbẹ titi, ṣugbọn ti wọn ko da a lohun, la gbọ pe o gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Bo tilẹ jẹ pe gbogbo akitiyan lati ba agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa sọrọ titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan lo ja si pabọ, ṣugbọn ti a gbọ pe iṣẹ iwadii ṣi n lọ lọwọ.
No comments:
Post a Comment