Gbajugbaja oṣere tiata nni, Oloye Binta Ayọ Mọgaji Odunẹyẹ, tọpọ awọn eeyan mọ si Igbanladogi ti ju bọmbu ọrọ sita, o ni alaṣẹwo lo pọ ju ninu awọn oṣere tiata lorilẹ-ede Naijiria, eyi to jẹ ki wọn maa wọ aṣọ iwọkuwọ lori itage.
O ni bi ki i ba a ṣe pe alaṣẹwo pọmbele ni wọn ni, ko yẹ ki obinrin to ba ni ọkọ gidi nile, to bimọ, to si
ni ẹbi rere de idi iṣẹ tiata, ko wa lọ maa ṣi ara rẹ silẹ tabi ṣe afihan ihooho rẹ bi
Ọlọrun ṣe daa sita.
Ayọ Mọgaji sọrọ naa lasiko to n kopa lori eto ileeṣẹ tẹlifisan kan ni Naijiria laipẹ yi, to si tu pẹẹrẹ-pẹẹrẹ ọrọ nibẹ.
Binta Mọgaji ni imura eeyan kan nigboro ni nkan ṣe
pẹluu idile to ti jade wa ati iwa ọmọluabi to ni, ti yoo si mu ko le ronu jinlẹ pe
iru oju wo ni aye fi n wo oun.
O sọ siwaju pe oun korira ki obinrin maa ṣi ara rẹ silẹ lasiko to
ba n ṣere itage, lati igba ti oun si ti bẹrẹ ere tiata, aye ko ri ihooho oun ju
ejika oun lọ.
Nigba to n dahun ibeere to nii ṣe lori awọn obinrin
onitiata to n ṣi ara wọn silẹ lati polowo ọṣẹ tabi ipara to n bo ara, Ayọ Mọgaji
salaye pe, ti eeyan ko ba maa polowo sinima onihooho tabi aṣọ ti wọn fi n luwẹ,
taa mọ si Bikini, ko si idi kankan fun obinrin lati ṣi ara silẹ, fi polowo ọja
kankan tabi fi fa oju awọn onibara rẹ mọra, nitori oju lasan ti to lati polowo
ọṣẹ tabi ipara.
O ni iwa ara bibo to wọpọ laarin awọn oṣere tiata
lọkunrin ati lobinrin lode iwoyi, ni ko ba oju mu, awokọṣe ṣaa ni awọn jẹ
lawujọ, bẹẹ si ni ohun ti eeyan ba ni lọpọlọ lo ja ju, kii se afihan ọyan, idi
abi ara bibo.
Igbanladogi to ti n sunmọ ogoji ọdun to bẹrẹ iṣẹ tiata sọ pe ọpọ igba ti oun ba wa ni ẹnu isẹ, ni oun
maa n tako abala ere to ba gba koun ṣi ara silẹ tabi wa ni ihooho, bẹẹ ni ẹnu oun
kii duro lati gba awọn ọjẹ wẹwẹ akẹẹgbẹ oun nimọran pe ki wọn dẹkun ṣiṣi ara
silẹ, tori eyi ko bojumu fun ọmọluabi ati aṣa Yoruba.
Lori awọn sinima to nii ṣe pẹlu afihan ihooho ati
iwa jagidi jagan abi lilo ibọn, O ni "Aṣa alaṣa ni a n
kọ pẹlu ṣiṣe fiimu onijagidijagan eyi to lodi si aṣa, iṣe ati ohun ajogunba wa
lorilẹ-ede Naijiria, idi si ree ti iwa ipanle ṣe n pọ si lorilẹ-ede yii."
Binta Ayọ Mọgaji, lasiko to n fesi lori bi awọn
oṣere tiata lode iwoyi ṣe n ri owo nidi iṣẹ naa ju awọn oṣere tiata aye atijọ
lọ ninu eyi ti Binta wa, oṣerebinrin naa ni, ohun ti onikaluku fi n
jẹkọ, abẹ ewe lo wa.
"Awọn osere tiata ti ẹ ro pe wọn n ri owo pupọ
lasiko yii ju asiko tiwa lọ, ṣe inu iṣẹ tiata yii naa lẹ ro pe wọn ti n ri owo
pupọ naa lati fi ra awọn ọkọ nla-nla ati awọn ile awoṣifila ti ẹ ro pe wọn ni yii?
"ṣe ẹ ko ro pe 'ẹbun' kọ ni awọn ile ati ọkọ naa, ti
kii si i ṣe inu iṣẹ tiata ti wọn n ṣe ni owo ti wọn fi ra awọn ohun meremere yii
ti wa?"
Lakotan, o rọ awọn akẹẹgbẹ rẹ lati maa ṣe ere to mu
ọgbọn lọwọ, ti yoo ṣe agbelarugẹ aṣa ati iṣe wa, ti yoo si kọ awọn araalu lẹkọ
gidi, nitori awokọṣe rere lo yẹ ki awọn onitiata jẹ lawujọ wa.
BBC
No comments:
Post a Comment