YAHOO-YAHOO: ỌWỌ TUN TẸ KỌLAWỌLE ATI DANIEL NI NASARAWA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 20, 2019

YAHOO-YAHOO: ỌWỌ TUN TẸ KỌLAWỌLE ATI DANIEL NI NASARAWA

Pẹluu ileri ti ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹede yi, iyẹn EFCC ti ṣe bayii, o ti fi han daju pe ko ni i pẹ ti wọn yo fi foju awọn afurasi ọmọ Yahoo ti wọn lọwọ tẹ l'Ọjọbọ ijẹta bale ẹjọ.

A gbọ pe awọn oṣiṣẹ EFCC ti ipinlẹ Kaduna lẹyin olobo ti wọn lawọn kan ta wọn gba ipinlẹ Nasarawa lọ, ti wọn si rọwọ to awọn gendekunrin meji kan, Kọlawọle aAdeshina, omọdun mẹtadinlọgbọn ati Ugochukwu Azolibe Daniel, toun jẹ ọmọdun mẹrinlelogun lagbegbe Ville Ayan to wa lẹgbẹ otẹẹli Princess Serah, Keffi.

Bọwọ ṣe tẹ wọn, a gbọ pe awọn nnkan bii ẹrọ Kọmputa alagbeeka, foonu olowo nla oriṣiriṣi, kaadi ipe (SIM Cards) oriṣiriṣi, kaadi owo (ATM) loriṣiriṣi ni wọn ka mọ wọn lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI