Titi di asiko ti a fi ko iroyin yi tan, inu ibanujẹ ọkan lawọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Bayelsa wa latari bi ọkan lara awọn Kọmiṣana ipinlẹ naa ṣe ku lojiji, to si mu kawọn eeyan maa beere lọwọ ara wọn pe 'ki lo le ṣẹlẹ'.
Pataki nnkan to mu ki iku Kọmiṣana fun ọrọ ijọba ibilẹ naa, Arabinrin Agatha Goma maa jẹ kayeefi fun ọpọ awọn eeyan ni bi wọn ṣe sọ pe ṣe ni obinrin naa sun lalẹ ọjọ Abamẹta to kọja yi, ti ko si ji lọjọ keji tii ṣe Aiku, ana an.
Obinrin ẹni ọdun marundinlọgọta naa la gbọ pe ilegbe awọn Kọmiṣana lo ku si kilẹ too mọ.
Bawọn kan ṣe n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe apeta ni, bẹẹ lawọn kan n sọ pe boya ironu ni, tawọn min in si n sọ pe asiko ẹ lo to, ṣugbọn ti ko tii sẹni to ye, ta a si gbọ pe iwadii ṣi n lọ lori iku to pa a.
Ọdun 2016 ni Gomina ipinlẹ naa, Seriake Dickson yan obinrin naa sinu ijọba, to si jẹ ọkan pataki lara awọn to duro ti Gomina Dickson gbamugbamu.
No comments:
Post a Comment