Ọjọ gbogb ni ti ole, ọjọ kan ṣoṣo ni t'olohun lọrọ tawọn eeyan fi n kọrin fun ogbologbo adigunjale kan ti wọn lo n dawọn akẹkọọ ile ẹkọ gbogboniṣe ti NEKEDE to wa niluu Akwa, ipinlẹ Anambra.
A gbọ pe ṣe ni ọdọmọkunrin naa tun lọ ọ ṣiṣẹ ibi, gẹgẹ bi wọn ṣe lo maa n ṣe e, ṣugtbọn ti omi pada dilẹ lẹyin asunṣujẹ ẹ, tọwọ si tẹ ẹ.
Ki wọn too dana sun, a gbọ pe wọn ti kọkọ luu lalubami, ti wọn si foju ẹ han fawọn ara agbegbe naa, ti wọn lawọn akẹkọ lo n gb ibẹ.
Bi wọn ṣe luu tan, la gbọ pe wọn ju taya sii lọrun, ti wọn si ṣa ina sii, ko pẹ ti wọn loo fi jona kọja sisọ.
No comments:
Post a Comment