WỌN DANA SUN ADIGUNJALE L'AKAWA IBOM NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 25, 2019

WỌN DANA SUN ADIGUNJALE L'AKAWA IBOM NITA GBANGBA

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi nnkan ti ọkunrin kan ti wọn dana sun lopopona Essien, agbegbe Ikot Ekpene nipinlẹ Akwa Ibọm ji gbe mulẹ, ṣugbọn sibẹ, iyalẹnu nla lo jẹ fun ọpọ awọn o rin si asiko nigba ti ju ina ọmọ ọrara sii lara, to si jona gburugburu.
 
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni awọn kan ni wọn n le ọkunrin naa bọ, ko too di pe awọn kan da a duro, ti wọn si bẹrẹ sii luu, ko too di pe wọn ju taya mọto sii lọrun, ti wọn si dana sun un.
 
Pupọ awọn to rii ni wọn n ba a kaanu, nigba to n bẹbẹ pe ki wọn foju aanu wo oun, ṣugbọn ti wọn ko ti ẹ gbọ, afigba ti wọn rii pe ẹmi jabọ lara rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI