WỌN BURA FAWỌN AARẸ ILẸ ẸJỌ KỌKỌ-KỌKỌ TI KO DIN L'ỌGBỌN NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 1, 2019

WỌN BURA FAWỌN AARẸ ILẸ ẸJỌ KỌKỌ-KỌKỌ TI KO DIN L'ỌGBỌN NIPINLẸ OGUN

Adajọ agba nipinlẹ Ogun, Onidajọ Mosunmọla Dipẹolu ti bura fawọn Aarẹ ile ẹjọ kọkọ-kọkọ ti ko din ni ọgbọn lonii niluu Abẹokuta.

Nibẹ lo ti gba gbogbo wọn lamọnran pe ki wọn lo anfaani naa lati fi gbe ofin ro, lai ṣe oju ṣaaju ẹnikẹni nigba ti wọn ba n gbe idajọ kalẹ, dipo bẹẹ ki wọn tẹle awọn ilana ofin.

Inu gbọngan ile ofin tuntun to wa lagbegbe Kọbapẹ, Abẹokuta ni eto naa ti waye, nibẹ ni Onidajọ Dipẹolu ti sọ pe yiyan ti wọn yan awọn Aarẹ tuntun naa ni lati mu eto idajọ wa sipele awọn araalu.

O ni lara awọn nnkan ti wọn yoo maa da si ni ọrọ ilẹ, ogun, igbeyawo atawọn nnkan min in, ti wọn yoo si maa gbe idajọ kalẹ nibamu pẹluu ofin to da wọn silẹ.

O wa a ran wọn leti pe ki wọn ma ṣe gbagbe awọn akọmọna ile ofin to sọ pe "Iṣẹ Takun-takun ati Esi", iyẹn Hardword and Result, eyi ti wọn mu ninu ọrọ Vince Lambard lati maa fi ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bo ti tọ.

Bẹẹ lo tun gba wọn lamọnran pe ki wọn yago fun abẹtẹlẹ, ọlẹ, imẹlẹ, ijẹra-ẹni-lẹsẹ, eyi ti ko ba ofin mu, dipo bẹẹ ki wọn fi ipo naa gbe iṣẹ naa larugẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI