Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, lawọn ara adugbo Ajiṣegiri lagbegbe Ilupeju nipinlẹ Eko ṣi n fẹhonu han lori bawọn ọlọpaa kogberegbe, iyẹn SARS ṣe yinbọn pa ọkan lara awọn to n gba ilẹ opopona kaakiri.
A gbọ pe awọn kan ti n wọn n ta igbo lawọn SARS naa n le kaakiri, ti wọn si da ibọn bolẹ laarin adugbo naa, ṣugbọn ti wọn ko ri ẹnikẹni mu balẹ ninu wọn.
Lara ibọn ti wọn yin yi, la gbọ pe o ṣeeṣi ba agbalẹ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Francis, to si jẹ pe loju ẹsẹ lo ti ku.
Lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo, Bala Ẹlkana sọ pe oun ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ati pe oun wa ninu ipade lasiko ti a kọ iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment