"Ọna atijẹ lo sun wa debẹ, ẹ foju aanu wo wa" lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n tẹnu baale ile ati iyaale ile kan, Nkiruka Ọkpara ti wọn lọmọ bibi agbegbe Ahiazu Mbaise nipinlẹ Imo ni ati Sunda Chukwuma toun wa lati agbegbe Isu, ijọba ibilẹ Onicha nipinlẹ Ẹbọnyi nigba tọwọ awọn Fijilante tipinlẹ Ẹbọnyi, iyẹn Ebonyi State Neighbourhood Watch tẹ wọn.
A gbọ pe wọn ti wa lẹnu iṣẹ tipẹ, ṣugbọn nigba taṣiri wọn maa pada tu sita, ọmọdun kan la gbọ pe wọn ji gbe labẹ iya ẹ ti wọn pe orukọ rẹ ni Chioma Njoku to n gbe labule Agbebo, ko too di pe akara wọn tu sepo.
AWIKONKO gbọ pe ṣe lawọn mejeeji yi gbimọ papọ lati ṣebi ẹni to fẹẹ ran iya ọmọ naa lọwọ lati maa ba a tọju ọmọ yi, nitori pe adagbe lo n ṣe.
Ilu Port Harcourt la gbọ pe wọn ti pamọpọ naa, ti wọn si ni Chukwuma gan an ni olori awọn to n ji ọmọ gbe kaakiri
Loju ẹsẹ ti wọn ni Chiọma ti ri ọwọ tawọn eeyan naa gbe, ati pe wọn ti ji oun lọmọ lọ, lo mu ko ke gbajare sita, tawọn yẹn si rọwọ to wọn.
No comments:
Post a Comment