Wọn ni ọjọ gbogbo ni ti ole,
ọjọ kan ṣoṣo bayii ni ti olohun, wọnyii lọrọ to lọ nibamu pẹluu bọwọ ṣe tẹ
ọdọmọkunrin kan ti wọn loo fẹran lati maa ji adiẹ gbe niluu Owode Yewa, ti wọn
si n kọrin “Akiti the ghost” fun un.
AWIKONKO gbọ pe iluu naa yoo
sinmi bayii, tawọn nnkan ọsin bii adiẹ ko nii ye e sọnu bii ti tẹlẹ mọ.
Ẹsun Mọnday ni wọn pe orukọ
ọdọmọkunrin naa ti wọn lọmọ ogun ọdun pere ni, ati pe iṣẹ ni wọn lo n kọ lọwọ
lagbegbe Tẹjuọla, Owode Yewa. Wọn ni lọpọ igba tawọn eeyan ba n wa adiẹ wọn,
anjọọnu ni wọn lero pe o n gbe awọn adie naa lọ.
Wọn lawọn eeyan ti kọju ija
sira wọn lọpọ, ti wọn ti fẹsun kan ara wọn lori adiẹ to n sọnu, lai mọ pe Mọnday
lo wa nidi ẹ. Igba to ya ni wọn lawọn eeyan gba kamu pe o ṣee ṣe ko jẹ pe
anjọọnu afẹfẹ lo kundun lati maa jẹ adiẹ lasiko yi.
Nigba taṣiri maa tu, wọn ni ṣe
lori tako Mọnday nigba to gba adugbo ọtọọtọ meji lọ, iyẹn adugbo Tẹjuọla ati
adugbo Mọlu Audu, to si lọọ ji adiẹ wọn ko, awọn kan ti wọn rin sasiko la gbọ
pe wọn rii nibi to ti n ji adiẹ gbe sabẹ aṣọ.
Lojiji ni wọn yọ sii to si fẹ
maa ba ẹsẹ rẹ sọrọ, ṣugbọn ti wọn gba tẹle, ta a si gbọ pe pẹluu iranlọwọ awọn
ẹṣọ alaabo So Safe Corps ni wọn fi rii mu. Bọwọ ṣe tẹ lo bẹrẹ sii ka boroboro
pe atijẹ lo sun oun debẹ.
Mọnday jẹwọ pe iya kan loun maa
n ta awọn adiẹ naa fun ni gbogbo ọjọ ni wọn ba ti n na ọja Owode, ati pe ẹẹdẹgbẹta
(500) naira loun maa n ta adiẹ kan ṣoṣo fun mama naa.
No comments:
Post a Comment