ỌWỌ TẸ JOHN TO N BA DUKIA ILEEWE JẸ NI SAPẸLẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 4, 2019

ỌWỌ TẸ JOHN TO N BA DUKIA ILEEWE JẸ NI SAPẸLẸ

Ko tii daju pe ọmọdekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni John Onerede yoo bọ ninu wahala to ko ara rẹ sii latari bi wọn lo ṣe n fojoojumọ gba dukia ile ẹkọ kan ti wọn pe ni Rhema International, eyi to wa lagbegbe Iwẹta, Sapẹlẹ nipinlẹ Delta jẹ.

AWIKONKO gbọ pe o ti ple loṣu mẹfa ti John ti wọn lojọ ori ẹ ko tii ju ọdun mẹẹdogun lọ ti maa wọnu ọgba ile ẹkọ naa, ti yoo si maa ba awọn dukia to wa nibẹ jẹ, ko da, ti wọn tun laimọye igba lo ti dana sun iwe awọn akẹkọọ.

 
A gbọ pe bo ṣe n ji owo naa lo tun n ji awọn nnkan to ba wulo fun un lawọn ọfiisi to wa nibẹ, to fi mọ ọfiisi ọga ileewe naa. Nigba taṣiri ẹ maa tu, a gbọ pe owo ọga ileewe naa to ji gbe lo gbagbe lasio to fẹ maa lọ.

 
Owo naa gan la gbọ pe ọga ileewe naa pada lọọ mu ko too ko si i lọwọ, to si na papa bora loju ẹsẹ, ṣugbọn ti ọga ileewe naa pariwo ole lee lori, ko too di pe awọn eeyan lee mu.

 
Bọwọ ṣe tẹ la gbọ pe o bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ tori pe o lawọn to n ran oun niṣẹ naa, ti wọn si muu gba teṣan ọlọpaa lọ ati lọọ fi to wọn leti, ṣugbọn iyalẹnu ni wọn loo tun jẹ nigba ti wọn lo tun n sọ pe ko sẹni to ran oun niṣẹ naa, bi ko ṣe ipinu oun.

 
Ṣa o, AWIKONKO gbọ pe awọn obi John ti n bẹbẹ pe ki wọn fi silẹ, ta a si gbọ pe ọga ileewe naa ti loun yoo gbọ ẹbẹ, iyẹn bi wọn ba tun awọn dukia ti John bajẹ ṣe, ki wọn si san owo to ti ji ko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI