ỌWỌ TẸ IYAALE ILE TO FẸ Ẹ JU ỌMỌ SỌNU L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 24, 2019

ỌWỌ TẸ IYAALE ILE TO FẸ Ẹ JU ỌMỌ SỌNU L'EKOO

Kani ki i ṣe pe awọn eeyan rin si asiko ni, boya iyaale ile kan ti a ko tii mọ orukọ ẹ dasiko ti a kọ iroyin yi tan ti ju ọmọ to bi funra rẹ sọnu, ko si ti na papa bora bayii, ṣugbọn ti aṣiri ẹ pada tu.

Agbegbe Ile-epo to wa nitosi Iyana-Ipaja niluu Ekoo niṣẹlẹ naa ti waye laarọ onii, iyẹn ni nnkan bi aago mẹwa aabọ aarọ.

AWIKONKO gbọ pe ibi ti iyaale ile naa ti n gbiyanju lati gbe ọmọ naa silẹ lọwọ ti tẹ, ti si bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, tori pe aisi owo lati fi tọju ara oun depodepo ọmọ naa lo mu koun pinu lati juu sọnu.

 
Nibẹ lawọn araalu ti mu iyaale ile naa lọ teṣan ọlọpaa Ile-epo fun alaye lẹkunrẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI