ỌWỌ TẸ IBRU, MONDAY ATI BISOYE, OGBOLOGBO ADIGUNJALE N'IJẸBU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 14, 2019

ỌWỌ TẸ IBRU, MONDAY ATI BISOYE, OGBOLOGBO ADIGUNJALE N'IJẸBU

Kani ki i ṣe pe awọn ọlọpaa rin sasiko tawọn ogbologbo adigunjale ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju ki wọn maa ja ọkada tuntun gba lọ lọwọ awọn to ni in ni, o ṣee ṣe ki wọn tun ti ri anfaani lati na papa bora, ki wọn si jẹ lọ bii iṣe wọn.

Oni la gbọ pe ọwọ ọlọpaa Odogbolu tẹ awọn ọdaran naa, Ibru Ogbẹba, Monday Wẹwẹ ati Bisoye Odubọtẹ lasiko ti wọn ja ọkada gba lọwọ ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Tanko Abdullah, to si jẹ pe loju ẹsẹ niyẹn ti figbe bọnu.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn bawọn ọdaran yi ba ti fẹẹ ja ọkada gba, wọn yoo lọ ra ata, ti wọn yii lọ ọ ja a lẹnu ẹrọ, yatọ si eyi, wọn tun mu irin ti wọn fi n tun nnkan (screw driver ati spanner) dani, ti wọn yoo si ṣebi ẹni fẹẹ gun ọkada.

Wọn ni ọlọkada to ba gbe wọn ru igi oyin, nitori pe ki wọn too rin siwaju daadaa, wọn yoo ti da ata naa si loju, ti wọn yo si fi awọn irin naa gun un lẹgbẹ, ko ma baa lagbara lati ba wọn ja, ti wọn yoo si gbe ọkada naa salọ.

Akara wọn la gbọ pe o tu sepo laarọ oni lasiko ti ọga ọlọpaa Odogbolu n kọja lọ, to si jẹ pe ariwo Tanko ni wọn gbọ, ti wọn fi lọ sibẹ, bi Tanko ṣe ṣalaye nnkan toju ẹ ri lawọn naa ti gba tọ wọn lẹyin, ti wọn si ri awọn mẹtẹẹta ko.

Bọwọ ṣe tẹ wọn, ti wọn n ko wọn lọ teṣan lawọn kan tun ti yọju lati jẹri gbe wọn pe bi wọn ṣe n ṣe niyẹ, ko da ti wọn ni ọkunrin kan to pe ara rẹ ni Michael Sunday naa tun yọju pe wọn ṣi gba ọkada lọwọ oun lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to kọja.

AWIKONKO gbọ pe awọn agbegbe bii Odogbolu, Ọsọsa ati Aiyepe ni wọn ti maa n jale juu.

Ni bayii, Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Bashir Makama ti sọ pe iru awọn ọdaran toun n wa lati fi jofin gan an lawọn mẹta yi, ti wọn yoo si de ile ẹjọ lati sọ idi pataki ti wọn fi n jale fun adajọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI