OṢIṢẸ IJỌBA TO N ṢẸGBẸ OKUNKUN HA SỌWỌ ỌLỌPAA, LO BA LOUN TI FI SILẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 18, 2019

OṢIṢẸ IJỌBA TO N ṢẸGBẸ OKUNKUN HA SỌWỌ ỌLỌPAA, LO BA LOUN TI FI SILẸ

Pupọ awọn to ri baale ile kan to pe orukọ ara rẹ ni Akinboun Tunji lọrọ ẹ n ya lẹnu, latari bi wọn ṣe ni ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun paraku ni, to si tun jẹ olori ninu ẹgbẹ okunkun Ayee. Wọn ni o ti le lọdun mẹwaa ti Tunji ti wọn ni oṣiṣẹ (non-teaching staff) ile ẹkọ imọ ẹrọ nipinlẹ Ogun, iyẹn Ogun State Institute of Technology to wa ni Igbẹsa ni.
Ohun ta a gbọ ni pe ọsẹ to lọ lọhun ni wọn laṣiiri Tunji tu lasiko to n ko awọn ọmọ kekeeke lọọ wọnu ẹgbẹ naa niluu Ijẹbu Ode, lai mọ pe awọn ọlọpaa SARS ti n dọdẹ wọn tipẹ niluu Ijẹbu Ode. Awọn kan ti wọn gbọ firinfirin pe Tunji fẹẹ mu awọn eeyan wọnu ẹgbẹ okunkun ni wọn lọọ ta awọn ọlọpaa SARS lolobo.

A gbọ pe bi Tunji atawọn to fẹẹ mu wọ inu ẹgbẹ naa ṣe gbọ pe awọn SARS ti wa nitosi wọn, lo mu ki wọn na papa bora, ta a si gbọ pe ọwọ tẹ diẹ lara wọn. Awọn tọwọ tẹ yi la gbọ pe wọn ka Tunji pe oun ni olori wọn to fẹẹ mu wọn wọle. Eyi lo mu ki wọn gba ọfiisi rẹ lọ lati lọọ gbe e.

Ṣe la gbọ pe awọn eeyan kawọ lori pe kayeefi nla lawọn ri, nitori ti wọn ko nigbagbọ pe ọkunrin naa le ṣe iru nnkan to jọ bẹẹ rara pẹluu bi oju ẹ ṣe tutu. Wọn ni bo ṣe de teṣan ọlọpaa lo bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, ati pe oun ko ṣe ẹgbẹ naa mọ, tori pe oun ti ṣetan lati jawọ ninu ẹ.

Ṣugbọn Tunji nigba to n sọrọ jẹ ko ye wa pe nnkan tawọn ọlọpaa sọ fun wa yatọ patapata si nnkan to ṣẹlẹ. O sọ ninu ọrọ rẹ pe “Kii ṣe nkan tawọn ọlọpaa sọ ni mo ṣe, mi o ṣe nnkan to jọ bẹẹ. Wọn ni mo fẹẹ mu awọn kan wọnu ẹgbẹ okunkun, ṣugbọn irọ lasan ni. Ibiṣẹ ni mo wa ti wọn ti wa a gbe mi".

Yatọ si Tunji ti wọn loo pinu lati fi ẹgbẹ naa silẹ pẹluu ilana labẹ ofin, bẹẹ lawọn min in tun fini fẹdọ sọ pe awọn ko ṣe ẹgbẹ adojutini naa mọ, tori pe wahala lo n ko wọn si lojoojumọ.

Bakan naa nigba to n b'AWIKONKO sọrọ, Kọmiṣana ọlọpaa, Bashir Makama sọ pe oun ko tii le fawọn eeyan naa silẹ, ayafi bi wọn ba pe awọn mọlẹbi wọn lati yọju, lati le ṣoju wọn, tori pe ti wọn tun pada mu wọn lori nnkan naa, wọn a le ṣe ẹlẹrii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI