Igbakeji Aarẹ orilẹede yi, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti ṣabẹwo ibanikẹdun si Alagba Reubẹn Faṣoranti to ẹ ọkan lara awọn agba ẹgbẹ Afẹnifẹre niluu Akurẹ lori iku ọmọ ẹ to waye lọjọ Ẹti to kọja yi.
Inu ibanujẹ nla ni Baba ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin (94) naa wa lasiko ti Ọjọgbọn Ọṣinbajo lọọ ṣabẹwo sii laarọ onii Aiku.
Nibẹ lo ti ṣeleri pe ijọba apapọ ti bẹrẹ igbesẹ lati da awọn ẹṣọ ologun sita yanturu kaakiri ilẹ Yoruba lati gbogun ti aisi eto aabo to peye, ati pe ki wọn rii daju pe ọwọ tẹ awọn to wa nidi iwa buruku naa.
Bẹẹ lo sọ pe koun too wa ṣabẹwo si baba naa, oun ti pe e lori aago lati ba a kẹdun.
Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Ondo naa ba Baba Reuben Faṣoranti kẹdun lori iku ọmọ ẹ, Arabinrin Funkẹ Ọlakunrin.
No comments:
Post a Comment