Ọ̀RUN ÀPÁÀDÌ N RÙN L'ÓRÍ TỌ́PẸ́ ÀLÀBÍ - AJÍHÌNRERE VICTOR EDET PARIWO SÍTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 28, 2019

Ọ̀RUN ÀPÁÀDÌ N RÙN L'ÓRÍ TỌ́PẸ́ ÀLÀBÍ - AJÍHÌNRERE VICTOR EDET PARIWO SÍTA

Pupọ àwọn tó rí ọ̀rọ̀ ikilọ tí Ajihinrere Victor Edet kò sórí ìkànnì ayélujára rẹ, ìyẹn Facebook láì pẹ́ yí ni wọn kò fẹ́ ẹ lè pá a dé pẹ̀lú bo ṣe sọ pé bí gbajumọ olórin ìgbàgbọ́ nnì, Ajihinrere Tọ́pẹ́ Alabi kò bá ṣọ́ra nípa imura rẹ, afaimọ ni kò má jẹ pe ọrùn àpáàdì ni yóò gbẹ̀yìn irin ajo ayé rẹ sii. 

Ajihinrere náà ni gbogbo àwọn irun onírun, ẹgba etí àti ọrùn, atike àtàwọn nnkan ẹ̀ṣọ́ ara tó ń lo lásìkò yí tí pọju nnkan amuyẹ ìjọba ọrùn lọ, nítorí náà, ó ní láti jawọ nínú ẹ. 

O gba Tọ́pẹ́ Alabi lamọnran pé kò má ṣe jẹ káwọn ohun àti àlùmọ́ọ́nì ayé yí bá ọrùn rẹ jẹ, nítorí kò má a dín lilo àwọn nǹkan náà kú, nítorí pé ó ti ń pọju pẹ̀lú bo ṣe ń lo wọn. 

Bákan náà lọ tún gbé oriyin fún gbajumọ olorin náà pẹ̀lú bo ṣe ń fáwọn orin rẹ gbé ìjọba Ọlọ́run lárugẹ káàkiri àgbáyé.

Ṣá o, báwọn kan ṣe ń gbé oriyin fún Edet náà làwọn kan ń bù ẹnu atẹ luu lórí ọ̀rọ̀ tó kọ náà, táwọn min in sì ń pe e ni ìránṣẹ́ èṣù. 




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI