ỌNỌREBU OLUBUNMI TUNJI-OJO FI ẸMI IMOORE HAN LORI BI WỌN ṢE YAN-AN GẸGẸ BI ALAGA IGBIMỌ TI YOO RI SỌRỌ IDAGBASOKE AGBEGBE NIGER DELTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 28, 2019

ỌNỌREBU OLUBUNMI TUNJI-OJO FI ẸMI IMOORE HAN LORI BI WỌN ṢE YAN-AN GẸGẸ BI ALAGA IGBIMỌ TI YOO RI SỌRỌ IDAGBASOKE AGBEGBE NIGER DELTA

Ọnọrebu Olubunmi Tunji-Ojo to n ṣoju ẹkun Akoko Ariwa Ila-Oorun ati Akoko Ariwa Iwọ-Oorun, ipinlẹ Ondo nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja ti fi ẹmi imoore rẹ han lori bi wọn ṣe yan an gẹgẹ bi alaga igbimọ awọn ti yoo ri sọrọ idagbasoke agbegbe Niger Delta, iyẹn Niger Delta Development Commission, NDDC.

Laipẹ yi ni wọn yan igbimọ ti yoo ri sọrọ NDDC nile igbimọ aṣoju-ṣofin, eyi to mu ki wọn yan Ọnọrebu Tunji-Ojo gẹgẹ bi alaga, bi wọn ṣe yan an naa lai ro tẹlẹ lo mu ko gbe oṣuba kare fawọn ti wọn mọ iwọn to gbe lati ṣiṣẹ naa bi iṣẹ.

Ninu ọrọ idupẹ rẹ, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ lopin ọsẹ yi lo ti sọ pe oun ko ni ṣai dupẹ gidigidi lọwọ Abẹnugọn ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Ọnọrebu Fẹmi Gbajabiamila, awọn olori atawọn ọmọ ile igbimọ naa pẹluu bi wọn ṣe fa oun kalẹ.


Pẹluu ọkan to kun fun imoore ati idunnu, mo ri i pe o ṣe koko lati dupẹ lọwọ Abẹnugọn ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Ọnọrebu Fẹmi Gbajabiamila, awọn olori ile atawọn ọmọ ile igbimọ yooku lori bi wọn ṣe yan emi atawọn min in mọ awọn igbimọ ti yoo ri sọrọ NDDC

Mi o ni ṣai dupẹ lọwọ awọn ẹlẹgbẹ mi patapata nilẹ igbimọ bi wọn ṣe fi ifẹ han si mi ṣaaju ati lẹyin ibura wa. Ifẹ to so wa pọ yoo tubọ maa jinlẹ sii pẹluu oore-ọfẹ Ọlọrun.

Oore-ọfẹ ti mi o lero ni bi wọn ṣe fi mi ṣe olori igbimọ NDDC. Eyi kii si ṣe nnkan min in bi ko ṣe anfaani lati ṣiṣṣ takuntakun, ti mi o si fẹ ẹ wo ti adojukọ atawọn nnkan ti mo le jẹ gẹgẹ bi ipenija pẹluu erongba awọn eeyan kaakiri orilẹede yi.

Mo fẹ ẹ fi da awọn ẹlẹgbẹ mi atawọn eeyan agbegbe ti wọn yan mi fun loju pe gbogbo anfaani ati agbara to ba wa nikawọ mi ni maa lo lati fi mu idagbasoke to lọọrin ba wọn, ti wọn yoo si ri apẹẹrẹ rere ninu igbesi aye wọn lai ṣe oju-ṣaaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI