ỌBASANJỌ DỌBALẸ FUN ỌBA AGURA TUNTUN NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 14, 2019

ỌBASANJỌ DỌBALẸ FUN ỌBA AGURA TUNTUN NITA GBANGBA

Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ tun ti ṣe bẹbẹ lonii Aiku niluu Abẹokuta, to si jẹ pe titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan ni ẹnu ṣi n ya ọpọ awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn, paapaa awọn to gbọ sii.

Bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe tuntun, ṣugbọn sibẹ, iwa baba naa lo jẹ kayeefi, to si mu ki wọn maa sọ pe loootọ lo bọwọ fun aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba.

Bẹ o ba gbagbe, Ọbasanjọ dọbalẹ fun Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi lasiko ti wọn ṣẹṣẹ gbe ade le e lori, ita gbangba loju gbogbo aye lo si ti dọbalẹ naa.

Nnkan to n ya awọn eeyan lẹnu tun ni bo ṣe jẹ pe Ipebi ni Balogun Owu naa, to tun jẹ Oluwo Ọjẹ niluu Gbagura ti lọọ na gbalaja fun Ọba Saburee Babajide Bakre.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI