Ofin tuntun bayii ti orilẹ-ede South Afrika gbe jade bayii ni pe ko si ọmọ Niajiria kan ṣoṣo ti yoo wọ ilu wọn lai gba iwe irinna, ati pe awọn ọmọ orilẹ-ede Ghana yoo pẹluu awọn ti yoo maa jẹ anfaani lati wọ ilu wọn nigba to ba wu wọn lai gba iwe irinna.
Bẹ o ba gbagbe, ati pe fawọn to ba mọ bi eto ọrọ aje South Afrika ṣe n lọ, orilẹ-ede Naijiria ni wọn ti n jere to pọju lagbaye, to si tun jẹ pe ko si orilẹ-ede naa lagbaye ti wọn le fọwọ sọya pe orilẹ-ede Naijiria kọ ni wọn ti n jẹ ere to pọju.
Orilẹ-ede meje ni awọn to n ri sọrọ irinna lorilẹ-ede South Afrika, iyẹn South Africa’s Department of Home Affairs gbe jade pe awọn ti fun wọn ni anfaani lati maa wọ ilu wọn lai gba iwe irinna lasiko to ba wu wọn, to si jẹ pe Naijiria ko si ninu wọn.
Minisita fun ẹka naa, Aaron
Motsoaledi lo kede ọrọ naa sita, to si tun jẹ ko di mimọ pe irin ajo afẹ lawọn tun fẹ maa fi pawo wọle sapọ ijọba wọn bayii, tori pe nnkan to gbe owo lori kaakiri agbaye lasiko yi ni.
No comments:
Post a Comment