O MA ṢE O, OBINRIN JA IBALE ỌMỌDUN MẸJỌ L'ONDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 14, 2019

O MA ṢE O, OBINRIN JA IBALE ỌMỌDUN MẸJỌ L'ONDO

Titi dasiko ti ẹ n ka iroyin yi lawọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣi n wa obinrin kan ti wọn fẹsun kan pe o fipa fi ọwọ ẹ ja ibale ọmọdun mẹjọ kan niluu Irele, ipinlẹ naa.

Bo tilẹ jẹ pe iroyin to lọ kaakiri igboro tẹlẹ ni pe ọkunrin kan tẹnikẹni ko mọ fipa ba ọmọ naa sun mọ inu ṣọọbu, to si salọ, ṣugbọn iya ọmọ naa ti wa a jẹ ko di mimọ bayii pe kii ṣe ọkunrin lo ja ibale ọmọ oun, bi ko ṣe obinrin.

Obinrin naa lo ṣalaye bọrọ ṣe jẹ fun ọkan lara awọn oniroyin to ba sọrọ lori foonu, to si ni awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lati mu ẹni naa, tori pe o ti na papa bora.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI