Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lori idi ti wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ṣe yinbọn pa akẹkọọ kan ti wọn ni idanwo aṣekagba ẹ lo ṣẹṣẹ pari, ki wọn too ran an niṣẹ de toru-toru.
A gbọ pe ile ẹkọ fasiti ti kan nipinlẹ Cross River, iyẹn Cross River University
of Technology ni akẹkọọ ti ko ti i mọ orukọ ẹ dasiko yi n lọ. Wọn ni bo ṣe n jade ninu yara idanwo ni nnkan bi aago mọkanla aabọ aarọ onii ni wọn lọọ pade ẹ pẹluu ibọn.
Wọn i bi wọn ṣe sọrọ diẹ ni wọn yinbọn mọn ọn nikun, to si ṣubu lulẹ loju ẹsẹ, tawọn yẹn naa si na papa bora.
Iwadii ṣi n lọ lọwọ lori awọn to pa ọdọmọkunrin naa.
No comments:
Post a Comment