MO TI GBA KADARA LORI ẸJỌ TIRUBUNAL - ADELEKE PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 6, 2019

MO TI GBA KADARA LORI ẸJỌ TIRUBUNAL - ADELEKE PARIWO SITA

Latigba tile ẹjọ Tribunal ti kede pe ọjọ Ẹti ana loun yoo da ẹjọ idibo ipinlẹ Ọṣun to kọja yi, eyi ti oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke pe lati fi tako esi ibo naa to wa laipẹ yi.

Bi idajọ naa ṣe n lọ lọwọ lawọn eeyan ti mọ pe ko sibi meji ti idajọ naa yoo jasi, bi ko ṣe pe Alaaji Gboyega Oyetọla ni wọn yoo kede gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori.

Loju ẹsẹ ti adajọ gbe idajọ ẹ kalẹ ni Sẹnetọ Adeleke ti sọ pe oun ti gba kadara, toun si tun ti gba kodoro lori idibo, ko da, toun ko ṣetan lati pe ẹjọ kankan mọ lẹyin eyi.

Inu atẹjade ti agbẹnusọ ẹ lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Ọlawale Rasheed gbe sita lo ti jẹ ko di mimọ pe eto oṣelu kii ṣe bo o ba, o pa, bi ko ṣe itẹsiwaju ati ibdanidọrẹ.

O si tun jẹ ko di mimọ pe gẹgẹ bii ẹni to n bọwọ fun ofin ilẹ wa, oun gbe oriyin fun Gomina Oyetọla fun bo ṣe bori lawọn ẹjọ ti wọn lọ gbogbo.

1 comment:

PÍN-IN KÁÀKIRI