Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Peter Ayọdele Fayọṣe tun ti ju bọmbu ọrọ gẹgẹ bo ṣe maa n juu nipa Aarẹ orilẹede yi, Ọgagun Muhammadu Buhari, to si loun pariwo titi fawọn ọmọ Naijiria p ki wọn ma ṣe dibo fun un.
Ori ikanni ayelujara ni Ayọdele Fayọṣe ti sọrọ naa nigba to n ba Alagba Reuben Fasoranti kẹdun iku ọmọ ẹ, Arabinrin Funkẹ Ọlakunrin tawọn agbebọn kan pa danu nipinlẹ Ondo lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.
O sọ pe ki Ọlọrun gba awọn ọmọ Naijiria ninu ijọba "Next Level" to jẹ ti ipaniyan, ijiniyan, airiṣẹ ṣe, iṣẹ, iwa ko-kan-mi ati ọrọ aje to n wọmi, to si ni oun ke to pe ki wọn ma ṣe tẹle ọrọ Buhari.
No comments:
Post a Comment