"Ẹfun nla ni, kii ṣoju lasan" lọrọ kayeefi to n tẹnu ọpọ awọn eeyan jade nigba ti wọn gbọ pe ọdọmọbinrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Mariya Sulaiman gun ẹgbọn rẹ toun jẹ ọmọ ọgbọn ọdun pa latari ọrọ ti ko nnkan.
Ọrun la gbọ pe Mariya ti wọn tun n pe ni Mulmulalliya ti gun ẹgbọn rẹ naa, Sani Sulaiman titi to fi ku lagbegbe Badawa Quarters to wa nipinlẹ Kano lopin ọsẹ to kọja yi, iyẹn ọjọ Abamẹta.
AWIKONKO gbọ pe awọn mejeeji wa ninu aawọ kan tẹlẹ, to mu ki wọn maa binu si ara wọn.
Ọjọ Abamẹta naa la gbọ pe awọn kan n ṣe igbeyawo niwaju ita ile awọn tẹgbọn taburo naa, ko pẹ ti wọn pari igbeyawo naa la gbọ pe Sani atawọn ọrẹ bẹrẹ idaraya ti wọn, ti wọn si n forin ọlọkan-o-jọkan gbafẹ.
Wọn ni pẹluu ibinu ni Mariya fi sọ pe ki wọn pa orin naa bi wọn ko ba fẹ wahala, ti wọn ni ẹgbọ rẹ ni kawọn eeyan ma da lohun, tori pe ojowu ni.
AWIKONKO ri igbọ pe nigba ti Mariya rii pe ṣe ni wọn fẹ maa foun ṣe yẹyẹ lo muu ko gba idi irinṣẹ orin naa lọ, lati pa a ni tipatipa, ṣugbọn tio wọn ni Sani ẹgbọn rẹ dii lọna lati paa.
Lojiji ni wọn sọ pe Mariya fa ọbẹ yọ, to si gun ẹgbọn rẹ lọrun, loju ẹsẹ lo ṣubu lulẹ to si dagbere faye. Awọn to wa nibẹ ni wọn sare gba tẹṣan ọlọpaa lọ lati lọọ fi to wọn leti, tawọn yẹn naa si gbera lati lọ.
Nigba tawọn ọlọpaa ri okodoro lo mu ki wọn gbe Mariya lọ tẹṣan wọn nibi to wa dasiko yi. Bẹẹ ni Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ naa, Ahmed Iliyasu ti paṣẹ pe dandan ni ki wọn foju ọdaran naa bale ẹjọ.
No comments:
Post a Comment