Iroyin tó tún ń lọ káàkiri orí ayélujára báyìí tún ní bí gbajúmọ̀ olórin Júù nnì, Yinka Ayéfẹ́lẹ́ ti sọ pé lóòótọ́ ni ìyàwó òun ti bímọ, ko da a, ibẹta làwọn ọmọ náà.
Gẹgẹ bí ìròyìn to tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ lónìí, obìnrin meji àti ọkùnrin kan ní wọn pé àwọn ọmọ náà, tó sì jẹ pe ilu Oyinbo níyàwó Yinka Ayéfẹ́lẹ́ bímọ sii.
Bẹ ó bá gbàgbé, ọjọ́ kẹfà oṣù kẹfà tó kọjá yìí niroyin náà kọ́kọ́ jáde sórí ayélujára, èyí tí AWIKONKO náà pẹ̀lú àwọn tó gbé e síta.
Ṣùgbọ́n ìyàlẹ́nu lo jẹ pe bí ìròyìn náà ṣe tán káàkiri tó, ní Yinka Ayéfẹ́lẹ́ fúnra rẹ gbà orí ìkànni ayélujára tí Facebook rẹ lọ, nibẹ lo sì ti sọ pé káwọn èèyàn má ṣe gba ìròyìn tó ń lọ káàkiri nípa òun náà gbọ́ rárá, àti pé ahesọ lásán ni.
Èyí ló mú kí gbogbo àwọn tó kọ ìròyìn náà tún yìí padà pé kò sí nnkan tó jọ bẹẹ rárá, àti pé nnkan rere ní wọn ń rò kan Yinka Ayéfẹ́lẹ́ ti ko tii lè dìde rìn lẹyin ogún ọdún tó ńijamba mọto.
Ní báyìí, ọkùnrin ọmọ bíbi Ìpínlẹ̀ Ekiti náà tún ti padà jẹ́ kó yẹ àwọn èèyàn pé lóòótọ́ niroyin tí wọn kọkọ gbọ́.
Ohun táwọn tó gbọ́ bí Yinka Ayéfẹ́lẹ́ ṣe kọ́kọ́ sọ pé ahesọ niroyin náà tẹ́lẹ̀ ń sọ ní pe ki kí ló dé tó ń pè àwọn èèyàn leke, tó sì ń mú àwọn oniroyin lonirọ, pàápàá nígbà tó tún jẹ́ pé ọkàn lára àwọn tó sunmọ ọn dáadáa lo tú àṣírí náà síta nígbà náà.
No comments:
Post a Comment