KO SI AWIJARE KANKAN LẸNU GOMINA DAPỌ ABIỌDUN, IṢẸ Ẹ NI KO KỌJU MỌ - ṢẸGUN ABIỌDUN JU BỌMBU ỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 25, 2019

KO SI AWIJARE KANKAN LẸNU GOMINA DAPỌ ABIỌDUN, IṢẸ Ẹ NI KO KỌJU MỌ - ṢẸGUN ABIỌDUN JU BỌMBU ỌRỌ

Kọmiṣana tẹlẹ fọrọ ilegbee (Housing), Ṣẹgun Abiọdun ti ju bọmbu ọrọ si Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun pe ko dakẹ gbogbo ọrọ ti ko lẹsẹ nilẹ to n sọ nipa Gomina ana, Ibikunle AMosun, paapaa nipa ti ileeṣẹ awọn onidajọ, iyẹn Judiciary Complex to wa loju ọna Kọbapẹ, Abẹokuta.

Laipẹ yi ni Gomina Abiọdun sọ pe ileeṣẹ naa ko ba ti igbalode mu, bi ko ṣe ti ọpọlọpọ ọdun sẹyin, ṣugbọn sibẹ, ọwọ tawọn agbaṣẹṣe fi n mu ọrọ kikọ naa pẹluu imẹlẹ, latari bi Gomina ana ṣe sọ pe oun ti san gbogbo owo tan fun wọn.

Ṣẹgun Abiọdun sọ pe ọrọ ti Gomina Abiọdun sọ naa ku diẹ kaato, to si jẹ ọrọ lati bu ẹnu atẹ lu gbogbo iṣẹ ti Gomina ana ṣe nipinlẹ Ogun, dipo bẹẹ, ko gbajumọ awọn iṣẹ ti wọn dibo yan an fun, tori pe ọna lati mu igbe aye irọrun ba ẹka eto idajọ nijọba ana fi ṣe agbekalẹ ile naa ti Gomina Abiọdun bu ẹnu atẹ luu.

O ni ki Gomina dẹkun laa maa bu igbo dudu ṣan fawọn araalu, nitori pe ọjọ karundinlọgbọn oṣu karun ọdun yi ni Aarẹ Buhari fi lọlẹ, ati pe yara igbẹjọ mẹtala, to fi mọ ọfiisi awọn Onidajọ, atawọn oṣiṣẹ, pẹluu yara ikawe lo wa nibẹ.

Bakan naa lo tun tẹnumọ ọn pe ọna lati ma ṣe pari awọn akanṣ iṣẹ ti Ibikunle Amosun ṣe silẹ lo n wa, ko le fi ri nnkan sọ pe awọn iṣẹ naa ko wulo fun awujọ, eyi ti ko si yẹ ko ri bẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI