ILE ẸJỌ PAṢẸ LODI SAWỌN AJAGUNGBALẸ TI WỌN FẸẸ GBA ILẸ-ONILẸ L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 4, 2019

ILE ẸJỌ PAṢẸ LODI SAWỌN AJAGUNGBALẸ TI WỌN FẸẸ GBA ILẸ-ONILẸ L'ABẸOKUTA

Ko sẹni to de ile ẹjọ giga to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun laarọ onii Tọside, ti ko nii mọ pe nnkan ayọ kan n ṣẹlẹ lori bawọn mọlẹbi kan ti wọn pe ni Akindipọ ṣe n fi idinnu wọn han lori aṣẹ tile ẹjọ giga kẹrin (Court 4) gbe kalẹ pe mọlẹbi naa lo ni ilẹ ti wọn n ja si lati bii ọdun marun sẹyin bayii.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe fi ye wa, wọn ni ilẹ kan ti ko din ni ẹẹka mọkandinlogun (19 Plots) to wa lagbegbe Ika-Ajibẹfun, nijọba ibilẹ Abẹokuta North ti wọn loo jẹ ti mọlẹbi Akindipọ naa, eyi ti wọn lawọn ajagungbalẹ kan wọ lojiji, ti wọn si fẹẹ fipa gba a lọwọ wọn.

Latigba naa la gbọ pe wọn ti bẹrẹ sii fa ọrọ naa, ti wọn si lawọn ajagungbalẹ naa ti da wahala rẹpẹtẹ silẹ lati gba ilẹ naa ni tipatipa.

AWIKONKO gbọ pe awọn ajagungbalẹ naa ni wọn pe orukọ wọn ni Alaaji Halidu Surakatu, Arabinrin Ṣọla Dahunsi Fatunbi, Ọgbẹni Ọlanrewaju Lukan Adeogun atawọn kan ti wọn n lo lati gbena woju awọn eeyan.

Wọn ni nigba tawọn mọlẹbi Akindipọ ti Alaaji Oloye Rilwan Alao Akindele to jẹ olori ẹbi wọn rii pe agbara wọn ko fẹẹ gbe wahala tawọn ajagungbalẹ naa n ba wọn fa, lo mu ki wọn sare gba ile ẹjọ lọ lati lọọ fẹsẹ ofin tọ ọ, eyi ti wọn lawọn ajagungbalẹ naa tun fẹsun ibanilorukọ jẹ kan wọn, ti wọn si pada da mọlẹbi Akindipo lare lori ẹ.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Ọnọrebu O. A. Ọnafọwọkan sọ pe gbogbo ẹri tawọn ajagungbalẹ naa mu wa lo tako awọn iwadii ti ile ẹjọ ṣe, paapaa ti agbẹjọro wọn ko si tun ni awọn ẹri aridaju lọwọ, ati pe  gbogbo itankitan tawon ajagungbalẹ naa n pa ko fibi kankan lẹsẹ nilẹ rara.

Bẹẹ lo paṣẹ pe kawọn ajagungbalẹ naa lọọ san ẹgbẹrun lọna igba ati aadọta (250,000) naira gẹgẹ bi owo itanran fun wahala ati iya ti wọn ti fi jẹ wọn lati nnkan bi ọdun marun sẹyin.

Nigba to n b'AWIKONKO sọrọ lori idajọ naa, agbẹjọro mọlẹbi Akindipọ, Ọgbẹni Ọladepo Onipẹde sọ pe idunnu nla lo jẹ foun nitori pe adadjọ naa ko ṣe ojuṣaaju, to si gbe idajọ kalẹ bo ti tọ.

O jẹ ko ye wa pe nigba kan lawọn ajagungbalẹ ti lọrọ lẹnu nipinlẹ Ogun, paapaa kaakiri orilẹ-ede Naijiria, ṣugbọn ni bayii, o ni wọn ko ni aaye kankan mọ latari ofin to de awọn ajagungbalẹ, ti wọn ko si nii gba wọn laaye mọ, tori pe ẹni tọwọ ba tẹ yoo fẹwọn gbara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI