IKU ỌLAKUNRIN: AARẸ ỌNA KAKANFO P'OWE OGUN NLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 14, 2019

IKU ỌLAKUNRIN: AARẸ ỌNA KAKANFO P'OWE OGUN NLA

...Bi wọn ba sun wa kan ogiri, abuku nla ni - Gani Adams

Iba Gani Adams to jẹ Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba ti sọ pe bi awọn to n fiya jẹ awọn ọmọ Yoruba kaakiri ilẹ wọn ko ba tete jawọ, ti wọn si sun wọn kan ogiri, abuku nla ni yoo jẹ nitori pe bi wọn ba fi le yi oju pada lati gbẹsan, ko ni sẹni ti yoo le duro.

Gani Adams to tun jẹ Olori ẹgbẹ ajijangbara nilẹ Yoruba, iyẹn Oodua Peoples Congress, OPC lo sọrọ naa jade lasiko to n bu ẹnu atẹ lu bi wọn pa ọkan lara awọn ọmọ agba ẹgbẹ Afẹnifẹrẹ, iyẹn Arabinrin Funkẹ Ọlakunrin.

Ninu ọrọ rẹ to n lọ kaakiri ori ayelujara ati iwe iroyin, eyi ti oludamọnran Iba Adams lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Kẹhinde Aderẹmi fi sita, Adams sọ pe "Ṣe la da bi i ẹwurẹ ti wọn n le kaakiri."

O ni Yoruba ki i dee de ja lai ni idi, eyi lo fa a, ti wọn fi n fọgbọn ṣe awọn nnkan to n ṣẹlẹ lasiko yi, nitori pe wọn ko fẹran ogun, ati pe kii ṣe pe ẹru atija lo n ba wọn, ṣugbọn awọn fẹ ki gbogbo agbaye mọ nnkan to n ṣẹlẹ, nitori pe wọn ko fẹẹ ja ija ẹbi.

Bẹẹ lo sọ pe "Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yi, Yoruba ti n sunmọ ogiri tan. O si ṣapejuwe iku Oloogbe tawọn Fulani darandaran pa naa gẹgẹ bi eyi ti wọn ko fẹ alaafia fun orilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ, o tun sọ pe "A kan fẹẹ jẹ ki gbogbo agbaye mọ awọn nnkan ti wọn ti ṣe fun wa atawọn eeyan wa, ati nnkan ti wọn ti ṣe sii. Ki wọn si le mọ awọn igbesẹ ti yoo tẹle awọn nnkan ti wọn ti n foju wa rii.

"Ki i ṣe pe a ko mọ ọna abayọ sawọn nnkan to n ṣẹlẹ yi, a kan fẹ ki gbogbo agbaye mọ pe kii ṣe ẹbi wa nigba ti a ba yi oju pada lati ja fun ẹtọ wa."

Bakan naa lo wa jẹ ko tun di mimọ pe gbogbo awọn agbaagba ilẹ Yoruba ni wọn ti n ṣepade lati bi ọsẹ meji sẹyin bayii lori bi wọn ṣe n dunkooko mọ ẹmi ati dukia awọn eeyan, ti wọn si n pe awọn Gomina ilẹ Yoruba lati mọ abajade ipade wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI